Iya Ọga Bello onitiata ti ku o!

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn oṣere, awọn afẹnifẹre atawọn ololufẹ ọkan pataki ninu awọn oṣere ilẹ wa, Adebayo Salami ti gbogbo eeyan mọ si Ọga Bello, n ki i fun ti mama rẹ, Alaaja Aishat Ayọka Abdulkareem, to jade laye

Ọmọ oloogbe naa, Ọga Bello, lo kọkọ kede iku iya rẹ lori ikanni Instagraamu rẹ, to si kọ ọ sibẹ pe ‘Pẹlu ọkan idupẹ ati ironujinlẹ ni mo fi kede iku mama mi ọwọn. Ni nnkan bii wakati diẹ ni Ọlọrun pe wọn sọdọ.

 ‘Ni deede aago meji ọsan oni (Tusidee) la maa sin wọn ni ilana Musulumi si Agboole Bello to wa ni Pakata, niluu Ilọrin.

‘Ẹ jọwọ, ẹ gbadura fun mama mi ati idile wa lasiko yii.’

Bi oṣere ti ọpọ ninu awọn ọmọ rẹ naa jẹ oṣere ṣe gbe ọrọ yii jade lawọn oṣere ẹgbẹ ẹ ti n ki i ku oriire.

Ọkan ninu wọn, Okunnu, sọ pe awọn ba a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ẹlẹyẹ ko ṣiwaju, ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

Bakan naa ni Bimbọ Ọṣhin, Muka Ray, Kẹmi Korede atawọn oṣere mi-in pẹlu awọn afẹnifẹre ti n ki i ku oriire pe o gbẹyin iya rẹ.

Leave a Reply