Iya ọlọmọ meji ku nibi ti oun ati ọrẹkunrin ẹ ti n ṣere ifẹ

Titi dasiko yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa ṣi ti ọkunrin kan, Lekan Agboọla, mọ ẹyin gbaga. Obinrin to n ba lo pọ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keji, to kọja yii, lo dakẹ mọ ọn labẹ, lọrọ ba di keesi.

Lugas ni wọn pe orukọ obinrin to di oloogbe yii, ọmọ meji lo ni lọwọ, bo tilẹ jẹ pe ko si nile ọkọ. Adamawa loun naa n gbe, ibẹ naa si ni Lekan n gbe to si ti n ṣiṣẹ. Iyawo Lekan gangan wa l’Ekoo pẹlu awọn ọmọ meji ti wọn bi.

Lekan Agboọla funra ẹ ṣalaye pe ọdun kẹta ree toun ati Lugas to doloogbe yii ti n yan ara awọn lale, awọn si maa n ṣere ifẹ daadaa lai si wahala kan.

O ni o pẹ diẹ toun ti ba a laṣepọ loun ṣe pe e lori foonu lọjọ naa pe ko maa bọ nile oun kawọn ṣere. Lekan sọ pe bi oloogbe naa ṣe de lawọn bẹrẹ ere wamọwamọ, afi lojiji toun ri i pe ko mira mọ, bẹẹ ni ko tiẹ mi mọ paapaa.

Agboọla gbiyanju, o gbe ololufẹ rẹ naa lọ si ọsibitu, ṣugbọn wọn sọ fun un pe oku lo gbe wa. Nipari gbogbo ẹ, teṣan lọrọ pari si.

Alukoro ọlọpaa l’Adamawa,DSP Suleiman Nguroje, sọ pe awọn yoo wadii iku obinrin to ku sabẹ Lekan yii, ayẹwo oyinbo yoo si tun tan imọlẹ si i.

Leave a Reply