Iya Rainbow ṣọjọọbi, o ni ẹbẹ pataki kan loun n bẹ Ọlọrun

Faith Adebọla, Eko

Ayẹyẹ ọjọọbi awọn gbajumọ oṣere ki i ṣe tuntun, tilu-tifọn lọpọ maa n ṣe e, wọn si maa n lo anfaani asiko naa lati dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aṣeyọri yoowu ti wọn ti ṣe nigbesi aye wọn ati lẹnu iṣẹ tiata, wọn tun maa n sọ erongba ọkan wọn ati afojusun wọn jade.

Iru asiko yii lo ṣẹlẹ si Abilekọ Idowu Philips, tawọn eeyan mọ si Iya Rainbow. Odu ni mama ẹni ọdun mọkandinlọgọrin yii nidii iṣẹ tiata, ki i ṣaimọ foloko rara. Bo tilẹ jẹ pe mama naa ko fi bẹẹ ṣere tiata rẹpẹtẹ mọ bii tigba kan, sibẹ bi onirese ko ba fingba mọ ni, eyi to ti fin silẹ ko le parun rara.

Ṣugbọn lọjọ Abamẹta, Satide yii, ni irawọ oṣere yii ṣọjọọbi ọdun mọkandinlọgọrin loke eepẹ, bo ṣe n dupẹ lọwọ Ọlọrun atawọn ololufẹ rẹ, mama naa sọ pe ẹyọ ẹbẹ kan ṣoṣo pere lo ku nigbesi aye oun toun fẹ k’Ọlọrun ṣe foun. Bayii lo ṣe sọrọ ọhun:

“Mo n ṣọọọbi mi lonii, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu (October), 1942 ni wọn bi mi. Ọjọọbi yii ni ọdun mọkandinlaaadọrin mi, inu mi si dun pe gbogbo agbaye lo n ba mi yọ. Mo ṣadura s’Ọlọrun Eledumare pe ko da ẹmi mi si, ẹbẹ pataki kan ṣoṣo ti mo ni si Ọlọrun ni pe ko da ẹmi mi si, ko daabo bo mi ki n pe ọgọrin ọdun, aadọrun-un ọdun titi di ọgọfa (120) ọdun loke eepẹ. Mo fẹẹ pe ọgọfa ọdun laye, paapaa tori iṣẹ ojiṣẹ Oluwa ti Ọlọrun ti gbe le mi lọwọ bayii. Mo ti da ijọ silẹ, mo si ṣadura k’Ọlọrun jẹ ki n pẹ laye lati ṣaṣeyọri iṣẹ mi.

Pẹlu bi mo ṣe dẹni ọdun mọkandinlọgọrin yii, mo ṣi lokun daadaa, mo ṣi n lọ soko ere, mo ṣi n ṣaraloge, mo ṣepolowo ọja gẹgẹ bii aṣoju ileeṣẹ, awọn iṣẹ wọnyi si n jẹ ki n maa ta kebekebe, ki n ṣi wa pa. Ṣugbọn bi mo ṣe maa n sọ, oore-ọfẹ Ọlọrun ni, keeyan ni ilera niru ọjọ-ori yii, ẹbun Ọlọrun ni. Oore-ọfẹ Ọlọrun ni pe mo ṣi wulo nidii iṣẹ tiata.”

Leave a Reply