Iyaale ile dawati n’Ilọrin, lawọn ọdọ ba ya bo ile Baba Kofo ti wọn fura si

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Iyaale ile kan, Muminat Usman, lo ti dawati lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ladugbo Guniyan, lagbegbe Alore, niluu Ilọrin.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ ọhun mu kawọn ọdọ adugbo naa ya bo ile ọkunrin kan ti gbogbo eeyan mọ si Baba Kofo, ẹni ti wọn fura si pe iṣẹ ọwọ ati irin rẹ ko mọ.

Ọjọ Tusidee ni wọn sọ pe Muminat kuro nile to si fi awọn ọmọ mẹrin silẹ. Ohun tawọn eeyan n sọ ni pe ile Baba Kofo lobinrin naa wọ gbẹyin ti wọn ko fi ri i mọ.

Latigba naa lawọn ọdọ ti n ṣọ ọkunrin naa, bi wọn ṣe ri i to n wọnu ile rẹ lọ ni wọn ya bo o.

Lara awọn araadugbo naa ṣalaye pe ki i ṣe igba akọkọ ree teeyan yoo dawati lagbegbe naa, wọn ni bii eeyan mẹrin ni wọn ti wa ti sẹyin.

Baba obinrin ti wọn n wa naa, Alhaji Hanafi Babatunde, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ Tusidee ni ọkọ rẹ pe oun pe ko wale.

Babatunde ni, “Awada ni mo kọkọ pe e, ṣugbọn nigba to pe mi lori foonu lọjọ keji pe lati ana lawọn ti n wa a ni mo too mọ pe loootọ nnkan ti ṣẹlẹ. Ọkọ rẹ ni ibi isọmọlorukọ aburo rẹ lo dagbere foun  lagbegbe Agaka, latigba naa ni wọn ko ti ri i.”

Akọroyin wa gbọ pe Ọjọruu, Wẹsidee, tọwọ tẹ Baba Kofo ni wọn ti fa a le ọlọpaa lọwọ fun iwadii to peye.

 

Leave a Reply