Ilaji ara iyaale ile yipada si maaluu lẹyin to ba ọkọ ọlọkọ lo pọ

Ẹyin obinrin tẹ ẹ maa n yan ale, afi kẹ ẹ ṣọra ṣe o, ale yiyan ti sọ iyaale ile kan to lọọ ba ọkọ obinrin mi-n lo pọ di maaluu. Idaji ara rẹ yipada si ti maaluu, ti o si ni iru nidii bii ẹranko.
Bo tilẹ jẹpe ki i ṣe orileede Naijiria niṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, ibi kan ti wọn n pe ni Tansanaia ni wọn niṣẹlẹ naa ti waye, sibẹ, arikọgbọn lo yẹ ko jẹ fun gbogbo awọn obinrin ti wọn maa n fẹ ọkọ ọlọkọ.
Ohun ta a ri gbọ gẹgẹ bi Linda Ikeji, oniroyin ori ayelujara ṣẹ gbe e, to si kọ ọ sibẹ pe ‘obinrin yii n yan ọkọ obinrin mi-in lale, nigba ti obinrin yii kẹẹfin ajọṣe rẹ pẹlu ọkọ rẹ, niṣe lo pawọ da si i’.
Ninu fidio obinrin yii to n ja rain lori ayelujara ni ẹsẹ rẹ mejeeji ti yipada si ti maaluu, ti iru si wa nidii rẹ, to n jo belebele bii ti maaluu.
Ẹkun ni obinrin naa bu si, to si n fi ede ilu wọn bẹbẹ pe ki wọn dariji oun. Bẹẹ ni awọn obinrin pupọ rọgba yi i ka, ti wọn si n fọwọ kan ẹsẹ rẹ to ti yipada si ẹsẹ maaluu naa.

Leave a Reply