Iyabọ Oko tun pada ji saye lẹyin wakati mẹta ti wọn kede pe o ti ku

Faith Adebọla

Ọpọ awuyewuye lo n lọ lori ipo ti gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa, Abilekọ Sidikat Odukanmi, tawọn eeyan mọ si Iyabọ Oko wa bayii, boya o ti ku ni abi o ṣi wa laaye.

Irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu ki-in-ni, ọdun yii, lariwo kọkọ gba ilu pe obinrin naa mi eemi ikẹyin, latari aisan ọlọjọ pipẹ kan to da a gbalẹ.

Ọkan ninu awọn irawọ oṣere ẹlẹgbẹ rẹ, Abilekọ Folukẹ Daramọla-Salakọ lo kọkọ fidi iku oloogbe naa mulẹ lori opo ayelujara rẹ.

Folukẹ kọ ọ sori atẹ Instagiraamu rẹ pe: “O ma ṣe o, afigba ti iku mu un lọ, sun un re o, Iyabọ Oko. A ṣe gbogbo ohun ti a le ṣe o, ṣugbọn o ye Ọlọrun.”

Bakan naa ni ọmọ oloogbe naa, Bisi Aisha, toun jẹ ṣọja, fidi iku mama rẹ mulẹ ninu awọn ọrọ ṣoki kan to sọ leralera, o ni: “Ki Ọlọrun tẹ yin safẹfẹ rere o, maami.” O tun ni: “Mọmi mi ti lọ, sun un re o, mama mi daadaa.”

Eyi lo mu ki ọpọ awọn oniroyin gbe ọrọ iku obinrin naa jade ninu iweeroyin ati lori atẹ ayelujara wọn.

Ṣugbọn laaarọ ọjọ keji, Ọjọbọ, Tọsidee, Aisha tun kọ ọrọ mi-in sori atẹ ayelujara rẹ, o ni: “Iṣẹ ara leyi o, mama mi tun gbe ọwọ wọn lẹyin wakati mẹta ti wọn ti ku. Titi aye la o maa fi iyin fun orukọ mimọ yin, Ọlọrun.”

Bakan naa ni Folukẹ Daramọla-Salakọ tun gba ori atẹ ayelujara rẹ lọ, toun naa si kọ ọ sibẹ pe: “Ẹ ma binu o, ọmọ rẹ lo tun ṣẹṣẹ sọ fun mi pe mama oun tun gbe ọwọ rẹ soke laipẹ yii, to fi han pe ko ti i ku, o ṣi wa laaye o. Aleluya. O ṣi wa laaye o.”

Ẹni ọdun mọkalelọgọta ni agba oṣere yii, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kọkọkanla, ọdun 1960, ni wọn bi i. Ọmọ bibi ilu Iwo, nijọba ibilẹ Iwo, nipinlẹ Ọṣun ni.

Lọdun to kọja yii ni ọkan ninu awọn ọmọ rẹ, Ọlamide, ṣiṣọ loju eegun aisan to n ṣe mama rẹ, o ni lati bii ọdun marun-un sẹyin ni mama oun ti dubulẹ aarẹ rọpa-rọsẹ kan ti wọn n pe ni Ischaemic stroke, aisan naa ni ko jẹ ko le lọ soko ere tiata bo ṣe maa n ṣe.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn onitiata ẹgbẹ ẹ dide iranwọ loriṣiiriṣii, sibẹ obinrin tawọn eeyan tun mọ si “Apoti Aje,” ati “Sisi Mama” yii ko gbadun taara, asiko kan tiẹ wa tawọn kan lero pe o ti ku.

Leave a Reply