Iyanṣẹlodi ẹgbẹ onimọto ko wahala ba’wọn araalu l’Ekoo

Faith Adebọla

Ọpọ awọn ero to fẹẹ wọ mọto lọ ibiiṣẹ aje wọn atawọn to fẹẹ rinrin-ajo ni wọn pẹ lawọn ibudokọ ero kaakiri ipinlẹ Eko lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu yii, latari bi wọn ko ṣe tete ri ọkọ gbe wọn, igba tọrọ naa si su awọn kan, niṣe ni wọn kẹsẹ sọna, wọn rin fun ọpọ wakati ki wọn too de ibi ti wọn n lọ.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn awakọ ero kan, labẹ ẹgbẹ ti wọn pe ni Joint Drivers Welfare Association of Nigeria (JDWAN) ṣe mu ileri wọn ṣẹ pe bẹrẹ lati ọjọ Mọnde ọhun, fodidi ọsẹ kan gbako, awọn o ni i gbe mọto jade tabi gbe ero, awọn maa bẹrẹ iyanṣẹlodi, titi tijọba yoo fi wa iyanju si ibeere ati aroye awọn.

Lara aroye naa ni pe owo tawọn alakooso ẹgbẹ onimọto tijọba faṣẹ le lọwọ, iyẹn Lagos State Parks and Garrages Management, eyi ti Alaaji Musiliu Akinsanya, ti wọn n pe ni MC Oluọmọ n ṣe alaga rẹ, n gba lọwọ awọn lojumọ ti pọ ju, o si n pa awọn lara kọja aala, wọn ni tikẹẹti oriṣiiriṣii ni wọn n ja fawọn, tipaa-tikuku si ni wọn fi n gbowo aitọ lọwọ awọn onimọto, wọn lawọn o le fara da iwa irẹnijẹ ati alọnilọwọgba naa mọ, afi tijọba ba wa nnkan ṣe si i lawọn yoo too bẹrẹ iṣẹ pada.

ALAROYE lọ kaakiri awọn ibudokọ lọjọ Aje, a ri awọn onimọto kan ti wọn paaki ọkọ wọn, ṣugbọn ti wọn o ṣiṣẹ, bo tilẹ jẹ pe ọgọọrọ awọn mi-in ṣiṣẹ lawọn gareeji bii Oṣodi ati Bọlade.

Ni Berger, wọn lawọn onimọto naa kọkọ ta ku lọwọ idaji, wọn o ṣiṣẹ, titi lọọ de ibudokọ 7Up, wa si Ikosi ati Ketu, lọọ Mile-12, ṣugbọn nigba ti yoo fi di iyalẹta, wọn ti bẹrẹ si i ṣiṣẹ.

Iwọnba awọn onimọto lo ṣiṣẹ lagbegbe Ikẹja, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọkọ ọhun ni wahala awọn agbero ko fi i bẹẹ wọpọ lọdọ tawọn.

Baba arugbo kan to n ṣiṣẹ fọganaisa lọna CMD Road sọ pe ẹsẹ loun fi rin lati Berger si 7Up laaarọ ọjọ naa. O nigba toun fi maa de ibiiṣẹ, o ti rẹ oun kọja afẹnusọ, niṣe loun kan jokoo soju kan.

Abilekọ Ṣade, sọ pe: “Ohun tawọn ijọba wa n ṣe ko daa o, tẹ ẹ ba ri ero pitimu nibudokọ laaarọ yii, o kọja sisọ. Ko si mọto. Ọkọ to yẹ ki n wọ ni ọọdunrun Naira, ẹẹdẹgbẹrin Naira ni mo pada wọ ọ, irinwo Naira lo gori ẹ lẹẹkan naa.”

Alaga ẹgbẹ awọn onimọto naa, Ọgbẹni Akintade Abiọdun, ba wa sọrọ lori aago. O ni iwọnba awọn ọkọ to ṣiṣẹ laaarọ ọjọ naa, boya awọn ọkọ to jẹ ti awọn MC Oluọmọ tabi awọn kọọkan ti wọn o fẹẹ dara pọ mọ iyanṣẹlodi tawọn ṣekede ẹ ni. O lawọn o ni i pada sẹnu iṣẹ, afi tijọba ba wa nnkan ṣe si ọrọ ilọnilọwọgba naa, atawọn ipenija mi-in to n koju awọn.

Gbogbo isapa wa lati ba MC Oluọmọ sọrọ ko seso rere, nitori ko si lọfiisi rẹ nigba ta a debẹ, bẹẹ ni ko dahun ipe lori aago rẹ.

Leave a Reply