Iyansipo Omiṣore yoo le awọn oloṣelu kan wọle l’Ọṣun – Oyetọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti sọ pe bi Senetọ Iyiọla Omiṣore ṣe di akọwe apapọ ẹgbẹ APC lorileede yii bayii yoo mu ki ọpọlọpọ awọn oloṣelu kogba wọle patapata.
Lasiko ayẹyẹ ikini ku aabọ tijọba ati ẹgbẹ APC l’Ọṣun ṣe fun Omiṣore ni gomina ti sọrọ naa.
O ni nigba ti oun wa lara awọn ọmọ igbimọ afunnṣọ ẹgbẹ naa, ọpọlọpọ awọn oloṣelu ni wọn bẹru oun, ni bayii ti Iyiọla Omiṣore ti waa di akọwe apapọ, pupọ wọn ni wọn yoo yago fun oṣelu patapata.
Oyetọla sọ siwaju pe “Ipinlẹ Ọṣun ati iha Iwọ Oorun Guusu orileede yii ti wa lẹnu ẹ bayii ninu iṣakoso ẹgbẹ APC. Mo wa n rọ ẹyin ọmọ ẹgbẹ lati bẹrẹ igbesẹ lori atunyansipo gomina mi, ẹ jẹ ka ṣiṣẹ papọ lati jawe olubori ninu idibo oṣu Keje, ọdun yii”

Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, Ọtunba Iyiọla Omiṣore dupẹ lọwọ awọn adari ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun fun aduroti wọn lori ipo tuntun to ṣẹṣẹ di mu naa.
O ni oun ko le gbagbe ipa ribiribi ti Aṣiwaju ẹgbẹ naa lorileede yii, Bọla Hammed Tinubu ati Oloye Bisi Akande, ko lati le jẹ ki erongba oun naa wa si imuṣẹ.
Omiṣore waa ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ nipinlẹ Ọṣun lati mọ pe iṣẹ pataki to wa niwaju wọn bayii ni idibo saa keji fun Gomina Oyetọla.
O ni oniruuru iṣẹ idagbasoke ti gomina naa ti bẹrẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun ko gbọdọ duro, bi wọn ṣe ṣugbaa oun naa ni wọn gbọdọ ṣugbaa gomina, ki ohun gbogbo le yọri si rere lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.

Leave a Reply