Iyatọ diẹ lo wa ninu Trump Amẹrika ati Buhari Naijiria    

O da mi loju pe ọpọ awọn ọmọ wa, ati awọn ti wọn jẹ agba paapaa ni wọn ti maa ri ibo ti wọn di kọja ni orilẹ-ede Amẹrika yii bii ohun ti ko kan wọn, ti wọn aa si ti sọ pe ki lo kan awọn nibẹ, ewo ni awọn ru ni tawọn. Ootọ ṣaa ni: wọn dibo ni Amẹrika, ki lo yẹ ko jẹ wahala tiwa. Ṣugbọn ọrọ aye yii ti ju bẹẹ lọ, aye ti lu jara gan-an, ohun to ba ba oju a maa ba imu, bẹẹ ni ko si ọlọgbọn kan nibi kan mọ, afi ẹni to ba fi ọgbọn ọlọgbọn ṣe ọgbọn nikan. Bi iru nnkan bayii ba ṣẹlẹ, ohun tawọn ọjọgbọn maa n ṣe ni lati ṣe ayẹwo ẹ finnifinni, ki wọn le wo ibi ti iru ọrọ bẹẹ ti gbe kan wọn, ki wọn si le mọ ọna ti wọn aa gbe iru ẹjọ bẹẹ gba to ba dọla, ati bi wọn ṣe le d a bi wọn ba ko o dewaju wọn. Ẹ fi ara balẹ, mo fẹẹ ṣe alaye awọn ohun kan ti ibo Amẹrika yii fi jọ ibo ti awa naa di kọja ni Naijiria lọdun to kọja, ati aṣiṣe ti awa ṣe ni tiwa.

Ko too di po a dibo yii ni 2019, iyẹn ibo ti a fi gbe Buhari wọle lẹẹkeji yii, emi pariwo titi, mo pariwo gan-an paapaa, mo si ṣe alaye idi ti a ko ṣe gbọdọ dibo fun Buhari mọ. Mo sọ ọ debii pe ti a ba dibo fun Buhari lẹẹkeji yii, aburu ti yoo ṣe fun wa, aa ju eyi to ṣe nigba taa dibo fun un lakọọkọ lọ. Awọn ti wọn gba mi gbọ ko to nnkan rara. Bi awọn kan ti n bu mi pe mo ti gbowo lọwọ PDP ni, bẹẹ lawọn kan n sọ pe ẹlẹyamẹya ti fọ mi lori. Awọn kan n sọ pe Bọla ni mo koriira, iyẹn ni mo ṣe ni ki awọn ma tẹle e lọ sibi to n lọ. Awọn kan ni bi awọn ko ba dibo fun APC, ṣe PDP ni ki awọn dibo fun ni, pe ole buruku ni PDP, awọn ko le dibo fun wọn. Awọn mi-in dide nigba naa, wọn ni Yoruba ni igbakeji Buhari, ọmọ wa ni, iyẹn Yẹmi, pe ko tilẹ yẹ ki n lẹnu lati sọ pe ki Yoruba ma dibo fun Buhari, afi ti mo ba jẹ alabosi nikan.

Ija ti awọn eeyan ba mi ja lasiko ibo naa le gan-an, koda, awọn ti wọn jẹ araale fun mi, ati awọn ọrẹ mi-in paapaa, yẹra fun mi, ti wọn n sọ pe o da bii pe mo ti gba nkan mi-in mọ ohun ti mo n ṣe yii, nitori ọrọ temi nikan lo ku to n ye mi. Ṣugbọn ibanujẹ lo n jẹ fun mi loni-in lati maa ri i pe gbogbo ohun ti mo sọ pe aa ṣẹlẹ lo n ṣẹlẹ, ti ọpọ awọn ọrẹ mi si n pada waa sọ fun mi pe ọrọ ti mo wi ṣẹ o, ti awọn ọmọlẹyin mi mi-in si n waa pada bẹ mi pe baba ẹ ma binu. Ṣugbọn kin ni mo ri gba ninu iyẹn: ọbẹ ge ọmọde lọwọ, ọmọde sare sọ ọbẹ nu, ṣe ọbẹ ko ti ṣe iṣẹ to fẹẹ ṣe ni. Apọnle wo lo wa fun mi ninu ki n sọ pe aburu fẹẹ ba Naijiria, ki aburu naa si maa ba a! Ṣe iyẹn waa jẹ nnkan daadaa lo n ṣẹlẹ si wa ni. Tabi bi aburu ba n ṣẹlẹ ni Naijiria, ṣe ko ni i kan emi naa ni!

Ṣugbọn o, ki gbogbo ọlogbọn mọ pe bi nnkan aa ṣe maa ri fun wa ree ti a ko ba ti n gbọrọ si ara wa lẹnu, tabi ki a maa di koko inu ọrọ mu, ki a maa wo igbẹyin ọrọ, ka too ba wọn ṣe e. Awọn ọlọgbọn kan sọrọ kan nigba ti a n ja ija ibo ẹlẹẹkeji Buhari yii: wọn ni ṣe emi ko mọ pe ole ni PDP ni, ati pe ti awọn ba dibo fun wọn lẹẹkan yii, wọn aa pada waa jale to buru ju eyi ti wọn ti ja tẹlẹ lọ ni. Mo ranti idahun ti mo fun wọn nigba naa daadaa. Mo pa aṣamọ ọrọ kan fun wọn ni. Mo ni ti eeyan ba kọle nla kan, to tun ni owo pupọ nile, tawọn adigunjale ba wa sile ẹ, o san fun un ko jẹ ki wọn ko ohun ti wọn ba fẹẹ ko ninu ile ẹ, ki wọn si ba tiwọn lọ, nitori bi tọhun ba wa laye, o le ko ọrọ to ju eyi tawọn adigunjale naa ko lọ jọ pada lọjọ iwaju, ṣugbọn to ba ti jẹ ki wọn pa oun, eleyii ko ni i ṣee ṣe mọ.

Lọna keji, mo sọ fun wọn pe ninu adigunjale ati ẹni to mura lati wo ile teeyan kọ to n gbe, ta lo yẹ ki eeyan gba laaye, mo ni o san ki wọn gba adigunjale laaye ko ṣe tiẹ, nitori bi adigunjale ba jale, yoo lọ, eeyan yoo si maa ri ile gbe ti yoo fi tun naro dide pada. Ṣugbọn awọn ti wọn fẹẹ wo ile ko ba rere wa, nitori bi wọn ba wole tan, wọn aa sọ tọhun di alarinkiri titi aye ni. Mo ni bo ba jẹ PDP nikan lo ku ni ẹgbẹ ti a le dibo fun, ka dibo fun un, ti wọn ba fẹẹ jale, ki wọn jẹ ki wọn jale, to ba si di ọdun mẹrin to n bọ, a oo fi ibo mi-in le awon naa lọ, a o si gbe ẹgbẹ mi-in wọle, bo jẹ ẹẹmẹwaa tabi ju bẹẹ lọ la n fi ibo yi awon oloṣelu yii pada, nigba to ba ya, Ọlọrun aa gbe ẹni kan dide ti yoo ba wa tun Naijiria ṣe. Ṣugbọn ti Naijiria ba ti wogba, ko si kinni kan ti ẹni kan yoo tunṣe mọ, kaluku aa di alarinkiri lasan ni.

Ohun ti mo n sọ gan-an ni wọn ṣe ni Amẹrika yii, iyẹn ni mo ṣe fẹ ka fi kinni naa ṣe arikọgbọn ati awokọṣe, nitori ọjọ iwaju. Wọn fi ibo yọ Donald Trump to jẹ Aarẹ wọn danu. Ki lo de ti wọn ṣe bẹẹ? Ṣe awọn ti wọn dibo fun Trump ni 2016 ko si laye mọ ni? Awọn ti wọn dibo fun un ni 2016 wa laye, bẹẹ lawọn mi-in tiẹ ti kun wọn ti wọn fẹran Trump. Ṣugbọn ninu gbogbo iwa ti Trumpp hu to bi awọn ara Amẹrika ninu, ko si eyi to buru ju iwa ẹlẹyamẹya ati ọta to da si aarin wọn lọ. Ki Trump too de sibẹ yẹn lawọn eeyan dudu ati eeyan funfun ti n gbe, orilẹ-ede to si gba awọn alejo laaye lati gbe igbe-aye wọn ni. Ṣugbọn ni gbara ti Trump de, ohun to bẹrẹ ni iwa elẹyamẹya, iwa lati gbe awọn alawọ-funfun gori awọn alawọ-dudu, to si n fẹnu ara ẹ sọ pe awọn alawọ-funfun ki i ṣe ẹgbẹ awọn alawọ-dudu.

Lojiji lawọn ara Amẹrika ri i pe awọn di ọta ara awọn, ti awọn alawọ-dudu ati funfun n ba ara wọn ja, ti wọn si n koriira ara wọn, ti wọn ko si ri ara wọn bii ọmọ Amẹrika kan naa mọ, ti iṣọkan to wa laarin wọn ti wọn ti n gbe bọ lati bii ọọdunrun ọdun sẹyin si n bajẹ loju wọn. Ohun to pa ijọba Trump niyẹn. Awọn ti wọn lọgbọn ninu awọn ara Amẹrika yii mọ pe ko le pẹ ko le jinna, iwa ẹlẹyamẹya ti Trump gbe de yii ni yoo yanju Amẹrika, oun lo maa pa orilẹ-ede naa, to maa sọ wọn di yẹpẹrẹ, ti o si ni i si apọnle kan fun wọn lawujọ agbaye. Idi ni pe ohun kan naa ti i maa ba gbogbo orilẹ-ede aye jẹ ni ainisọkan. Nigba ti orilẹ-ede tabi ilu nla kan ba wa ti wọn ko le fi ohun kan sọrọ nibẹ, ogun araata ni yoo pada ko wọn lọ, awọn ti ko si to wọn ni yoo pada ko wọn lẹru: nitori iṣọkan nikan lo le sọ orile-de kekere di nla!

Nibi yii ni gbogbo awọn ti ọrọ ye ni Amerika ti pa ọro ẹsin tabi ẹya ti, ti wọn gbe ọrọ oṣẹlu ti si ẹgbẹ kan, ti wọn pinnu lati fi ibo leTrump lọ. Ti ẹ ba ri i daadaa, ti ẹ ba si mọ itan Amẹrika, ko si ibo kankan lọdọ wọn to da iru wahala to to tasiko yii silẹ ri, ohun ti ko ṣẹlẹ ri l’Amẹrika ṣẹlẹ lasiko Trump, ọta to si ti wa laarin wọn bayii, iṣẹ nla ni ẹni to ṣẹṣẹ fẹẹ gbajọba yii yoo ṣe lati ri i yanju. Idi ni pe awọm alawọ-funfun ti ri ara wọn bii ọga awọn alawọ-dudu nibẹ, gẹgẹ bi awọn Fulani ati Hausa ti ri ara wọn ni Naijiria bayii bii pe awọn ni Ọlọrun fun gbogbo wa. Buhari lo da eyi silẹ, o n gbe Fulani gori awa to ku, o si ti ibi eyi sọ wa di ọta ara wa. Ọta naa ti gbilẹ, lojoojumo lo si n ran si i. Ko si bi kinni naa o ṣe ni i di ogun lọjo iwaju, bo ba si dogun, afaimọ ko ma jẹ orukọ mi-in ni Naijiria yoo pada jẹ, nigba ti ogun ba tu gbogbo wa ka.

Bẹẹ bo ba ṣe pe a panu-pọ lati fi ibo yọ Buhari ni, aburu to fi ọdun mẹrin ṣe iba mọ niba, a ba si tete ri ibi yanju iṣoro wa. Ati pe ọrọ naa yoo ba ẹni yoowu to ba gbajọba lẹru, aa maa bẹru pe awọn araalu le fi ibo yọ oun naa, aa si tori eyi ṣe daadaa. Ṣugbọn a ti sọ anfaani yii nu, ki Ọlọrun ma jẹ ko pada buru fun wa ju bayii lọ ni. Nitori ẹ la ṣe gbọdọ fi ọrọ ibo Amẹrika yii ṣe ọgbọn, nitori iru rẹ yoo tun pada ṣẹlẹ lọdọ wa.

Leave a Reply