Iyawo Buhari bẹ ọmọ Naijiria: Loootọ nijọba ọkọ mi ko daa to, amọ ẹ foriji wa  

Faith Adebọla

“Ẹyin ọlọla to wa nikalẹ, ẹyin alejo pataki pataki gbogbo, ẹyin ẹni iyi lọkunrin lobinrin, gẹgẹ bẹ ẹ ṣe mọ pe ijọba yii ti n kogba sile lọ, to si ṣee ṣe ko jẹ ajọdun ominira to kẹyin ni saa iṣakoso wa leyi ta a n ṣe yii, mo gbadura fawọn ọmọ Naijiria, mo si fẹ kawọn naa gbadura pe ki eto idibo ati igbejọba-funni to n bọ yọri si rere.

“Ijọba wa yii le ma dara to, o lawọn kudiẹ-kudiẹ tirẹ, ṣugbọn mo fẹẹ lo anfaani ọjọ oni lati tọrọ aforijin lọwọ awọn olukọ ẹsin Islam ati gbogbo ọmọ Naijiria lapapọ. Mo bẹ yin ni o, gbogbo wa la gbọdọ ṣiṣẹ papọ ki Naijiria le dara ju bayii lọ fun wa.”

Eyi ni diẹ lara awọn ọrọ ẹbẹ to jade lẹnu Abilekọ Aishat Buhari, iyawo olori orileede wa, Muhammadu Buhari, lasiko eto adura akanṣe kan ti wọn fi sọri ayẹyẹ ajọdun ominira kejilelọgọta ti Naijiria kuro labẹ akoso awọn oyinbo amunisin.

Gbọngan apero mọṣalaaṣi apapọ ilẹ wa niluu Abuja, leto naa ti ṣẹlẹ nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ to kangun si ayajọ ominira to waye lọjọ Satide,  ọjọ ki-in-ni, oṣu Kẹwaa yii.

Gẹgẹ bi Aisha ṣe sọ, o ni bi awọn owo ilẹ okeere ṣe n fẹyin Naira janlẹ lọja agbaye ti mu ki ọrọ-aje dẹnu kọlẹ, ti eyi si ti fa inira gidi fawọn araalu lori eto ẹkọ, eto ilera ati igbokegbodo ojoojumọ wọn.

Sibẹ, obinrin naa gboṣuba fawọn ologun atawọn ẹṣọ eleto aabo mi-in fun iṣẹ takun-takun wọn lati kapa ipenija awọn ajinigbe, awọn afẹmiṣofo, awọn agbebọn atawọn ọbayejẹ mi-in ti wọn o jẹ ki omi alaafia orileede yii toro.

Aisha ni: “A gbọdọ pawọ-pọ ja lodi si ipenija aabo yii ni. Loootọ la mọ riri isapa tijọba n ṣe, ṣugbọn o yẹ ka mẹnuba a pe awọn eto loriṣiiriṣii nipa iṣẹ agbẹ, dida ileeṣẹ silẹ, riro awọn ọdọ atawọn obinrin lagbara ki wọn le ri ipese amaratuni gba, ki wọn si rọna lọ.

Emi tikara mi lo ajọ ‘Aisha Buhari and Future Assured’ ti mo diidi da silẹ lati lati mu igbe aye rere ba awọn obinrin ẹlẹgbẹ mi, awọn ọdọ atawọn ọmọde, mo si ti lo ajọ yii lati ro ọpọ eeyan lagbara,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply