Iyawo fẹẹ kọ ọkọ ẹ, nitori to kọ lati gba abẹrẹ Korona

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an yii, ni tọkọ-taya Graham ati Chanelle Spices, ni Cape Town, lorilẹ-ede South Afrika, yoo tọwọ bọwe iwe ipinya, ti wọn ko ni i fẹ ara wọn mọ, afi bi ọkọ ba gba abẹrẹ to n dena Korona ko too di ọjọ naa. Ai jẹ bẹẹ, iyawo ti loun yoo kọ ọ silẹ ni.

Ọdun 2003 lawọn tọkọ-taya yii ṣegbeyawo, wọn jọ n gbe lai si wahala, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i bimọ funra wọn. Afi lọdun 2020 ti Korona de, to mu Graham, to si ku diẹ kọkunrin naa ku patapata.

Iyawo rẹ to fẹẹ kọ ọ silẹ yii sọ fẹka iroyin News24 pe, “Graham ko Korona lọdun to kọja, oju mi bayii ni mo ṣe n wo o to n ku lọ. Bi ko ṣe ku paapaa jọ mi loju, iyanu gbaa ni, nitori o ni aisan ikọ seeemi-seeemi( asthma). Korona yẹn tun waa mu iha rẹ, ti ko le mi daadaa rara, iyanu gbaa ni bo ṣe bọ ninu ẹ.

“Emi o le fi ẹmi mi tafala, mi o dẹ le gbe pẹlu ẹni ti ko ṣetan lati daabo bo ara ẹ atawọn to sun mọ ọn. To ba ti kọ lati gba abẹrẹ Korona yii, mo maa kọ ọ silẹ ni’’

Ṣugbọn Graham sọ pe oun ko fi bẹẹ nigbagbọ ninu abẹrẹ yii. O loun ko fẹ kẹnikan waa fi oun dan abẹrẹ Korona wo, nitori ko sohun to fi da wa loju pe iwosan pọnbele ni abẹrẹ naa.

Ọkunrin naa tẹsiwaju pe oun nigbagbọ ninu sayẹnsi loootọ, ṣugbọn o ni ibi to de, oun ko fẹẹ gba abẹrẹ Koro yii, o si dun oun pe ọrọ abẹrẹ naa lo fẹẹ fopin sigbeyawo ọdun mejidinlogun tawọn ti n ba bọ.

O loun atiyawo oun ti jọ sọrọ yii titi, ṣugbọn ibi pẹlẹbẹ naa lọbẹ fi n lelẹ. To ba si di lọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an yii, awọn yoo lọ si kootu lati tọwọ bọwe ipinya.

Leave a Reply