Iyawo gomina Ọyọ ṣeranwọ fawọn ibeji ti iya wọn ku lẹyin to bi wọn tan ni Ṣaki

Olu-Theo Omolohun Oke-Ogun

Bi eeyan ba gẹṣin ninu awọn mọlẹbi Balogun laduugbo Koomi, niluu Ṣaki, lasiko yii, onitọhun ko ni i kọsẹ pẹlu bi ijọba ibilẹ Onidagbasoke ipinlẹ Ọyọ ṣe dẹrin-in pẹẹkẹ wọn latari bi idile naa ṣe padanu Abilekọ Afusat Balogun, ẹni ọdun mejidinlogoji to padanu ẹmi rẹ lẹyin to bi ibeji tan.

Iṣẹlẹ to gbomi loju eeyan ọhun ṣẹlẹ lọsẹ meji sẹyin nileewosan ijọba to wa niluu naa, nigba ti oloogbe to bi bimọ meji tẹlẹ ọhun bi awọn ibeji, ọmọkunrin ati ọmọbinrin kan, ṣugbọn ti ko ṣee ṣe fun un lati wo oju awọn ọmọ naa to fi dagbere faye.

Lakooko to n fi awọn ẹbun ati eto iranwọ jiṣẹ fun idile oloogbe naa, iyawo gomina ipinlẹ Ọyọ, Iyaafin Olufunkẹ Makinde,

ẹni ti iyawo alaga ijọba ibilẹ naa, Alaaja Adenikẹ Adeleke Continental, gbẹnu rẹ sọrọ sọ pe nigba toun gbọ nipa iṣẹlẹ yii, o ka oun lara, o si dun oun wọnu egungun tori abiyamọ loun naa, oun si mọ bi ewu ọjọ ikunlẹ ṣe lagbara to.

O ni eyi lo mu ki oun tete ṣeto iranwọ fawọn ibeji ti ko niyaa mọ ọhun.

Lara awọn ẹbun ti wọn fun wọn ni irẹsi, ẹwa, miliiki alagolo ati ọpọ aṣọ ọmọde loriṣiiriṣii, bẹẹ ni wọn si tun fun wọn lẹbun owo.

Alaaja Adeleke ni ko sẹni ti ko mọ bi akoko ta a wa yii ṣe ri, pe ogunlọgọ eeyan to ṣi ni obi ni ko le jẹun kanu lẹẹmẹta loojọ, ka ma ṣẹṣẹ waa sọ nipa awọn ikoko ti ko niyaa.

O waa gba a ladura pe k’Ọlọrun dawọ ibi duro, ko si da awọn ibeji naa si. O ni ijọba ibilẹ naa yoo maa kan si wọn loorekoore tori ọmọ ijọba lawọn ọmọ naa.

Nigba to n tẹwọ gba ẹbun ọhun, ọkọ oloogbe, Ọgbẹni Mufutau Balogun, fẹmi imoore han si aya gomina Ọyọ ati alaga ijọba ibilẹ naa fun ọrọ itunu ati ifẹ ti wọn fi han si wọn, o loun mọ ohun ti wọn ṣe naa loore.

Leave a Reply