Iyawo ile kọ lẹta si gomina Eko, o lọkọ oun maa n fipa ba oun atọmọ lopọ

Gbajumọ ọmọ jayejaye kan niluu Eko, Ọgbẹni Temidayọ Lucky Kafaru, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Lascatter niyawo ẹ ti fẹsun ifipabanilopọ kan, bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa ti sọ pe niṣe lo fẹẹ ba oun lorukọ jẹ.

Arabinrin Diana Faith Logico, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun, ti sọ pe ọkọ oun, ẹni to gbajumọ daadaa nigboro Eko maa n fi ipa ba oun lo pọ, bẹẹ lo tun ni awọn iwa buruku kan to maa n hu pẹlu ọmọkunrin toun bi fun un ti ko ti i ju ọmọ oṣu marun un pere lọ.

Ninu iwe ti obinrin yii kọ ranṣẹ si Gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu, to si tun fi ẹda ẹ ṣọwọ si ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, Ọgbẹni Mohammed Adamu, atawọn mi-in tọrọ ọhun kan lo ti ni ki wọn gba oun lọwọ iya ti ọkunrin naa fi n jẹ oun ati ọmọ.

Lara ohun ti Faith ba awọn oniroyin sọ ni pe ọkọ oun maa n gbe kinni ẹ si ọmọ lẹnu, bakan naa lo ti fipa ba ọmọọdọ awọn sun ri, to si maa n fipa ki oun naa mọle daadaa.

Ṣugbọn Temidayọ, ọkọ obinrin yii, ti sọ pe ko si ootọ kankan ninu gbogbo ẹsun to fi kan oun, ati pe niṣe lo mọ-ọn-mọ fẹẹ ba oun lorukọ jẹ.

O loun ko ba ọmọọdọ kankan sun, bẹẹ loun ko hu iwa ibajẹ kankan pẹlu ọmọ t’obinrin naa bi foun. Bakan naa lo tun sọ pe gbogbo ẹsun ti iya iyawo oun, Arabinrin Edwina Logico. ati ọmọ ẹ n ka soun lẹsẹ yii, ibajẹ eniyan ni o, wọn fẹẹ fi ba oun laye jẹ ni.

Ni bayii, Ọgbẹni Bamidele Ogundele, agbẹjọro fun obinrin yii loun ti fọrọ naa to igbimọ to n ri si iwa ifipabanilopọ ati fifi iya jẹ ni lọna ti ko tọ laarin lọkọ-laya leti ni ọfiisi wọn ni Alausa, Ikẹja. l’Ekoo, ṣugbọn gbogbo akitiyan igbimọ naa lati fọrọ wa ọkunrin yii lẹnu wo ni ko so eso rere.

 

Leave a Reply