Iyawo kọ Baba Ibeji silẹ, lo ba gbe majele jẹ l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bo tilẹ jẹ pe ọsẹ to kọja lo ṣẹlẹ, awọn eeyan ko ti i yee sọrọ nipa iku ojiji ti ọkunrin kan, Akinọla Imọlẹayọ Abayọmi tawọn eeyan mọ si Baba Ibeji, fi para ẹ l’Abẹokuta. Majele buruku lo mọ-ọn-mọ fi owo ara ẹ ra, to si da a mu, bẹẹ wọn ni iyawo ẹ to kọ ọ silẹ lojiji lo jẹ ki ọkunrin naa gbe majele jẹ.

  Ẹni ọdun mejilelọgbọn pere ni Baba Ibeji, Agọ-Oko lo n gbe l’Abẹokuta pẹlu iyawo rẹ to kẹru jade nile loṣu kẹta, ọdun yii atawọn ibeji.

ALAROYE gbọ pe ọkunrin yii maa n lu iyawo naa ju lọpọ igba, to jẹ awọn araale lo maa n ba wọn da si i. Iya to ni ile ti wọn n gbe ni wọn si lo maa n fa wahala yii, nitori ija ti oun ati Iya Ibeji maa n ba ara wọn ja.

Lilu naa lo pọ ju fun Iya Ibeji, bo ṣe kẹru kuro nile ọkọ ẹ lọjọ karun-un, oṣu kẹta niyẹn, to ni oun ko le jẹ ko waa lu oun pa nitori iya onile.

Lẹyin ija naa, Baba Ibeji lọọ bẹ iyawo ẹ pe ko pada wa sile, oun ko ni i lu u mọ. A gbọ pe obinrin naa loun ti gbọ ẹbẹ rẹ, ṣugbọn o ni afi bi ọkọ oun ba le ko jade ninu ile naa loun ati ẹ yoo tun jọ maa gbe. O loun ko le pada sinu ile ti wahala ti n ṣẹlẹ laarin awọn naa mọ.

Aipada sile Iya Ibeji ko dun mọ ọkọ rẹ, wọn ni ara rẹ ko fi bẹẹ ya gaga mọ, ati pe o maa n ronu pupọ, o si n gbe gbogbo igbesẹ lati ri i pe obinrin naa pada wale pẹlu awọn ọmọ.

Afi bo ṣe di l’Ọjọbọ ọsẹ to kọja yii, ti ọkunrin to n ṣiṣẹ awọn to n tẹ nnkan sara aṣọ, baagi ati bẹẹ bẹẹ lọ naa kuro nibi iṣẹ, to dagbere ile fawọn eeyan lọwọ irọlẹ, to si ra oogun apakokoro ti wọn n pe ni Sniper ati eyi ti wọn fi n pa eku ti wọn n pe ni Push out, bẹẹ lo tun ra majele kẹta tiyẹn naa wa ninu igo dudu.

Bo ṣe dele lo wọ yara ẹ, o po awọn majele naa pọ, o si gbe e mu. Nigba ti awọn araale  yoo fi maa gburoo ẹ to n kigbe inu, ẹpa ko fẹẹ boro mọ, nitori o ti n yọ ifoofo lẹnu.

Wọn pe iyawo ẹ ati aburo ẹ lori foonu lati fi to wọn leti, ki wọn si le ri i, ṣugbọn nnkan ti bajẹ, akukọ ti kọ lẹyin ọmọkunrin.

Iyawo rẹ ti wọn lo tori ẹ jẹ majele naa ti sọrọ, o ni ija awọn ti pari, nitori Baba Ibeji maa n pe oun lori foonu daadaa. Koda, o maa n sọ pe koun ba oun gbe omi wa sile, oun yoo si gbe e lọ fun un.

Iya Ibeji sọ pe ile naa loun ko fẹẹ pada si, ki i ṣe pe oun ko fẹ ọkọ oun mọ, o loun ko mọ idi ẹ to fi gbe majele jẹ.

Leave a Reply