Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Mọto kankan ko kọ lu wọn, ere ti ọkunrin to wa mọto naa n sa ni wọn lo pọ ju, to bẹẹ to fi padanu ijanu ọkọ, to si mori le inu igbo, iyẹn lagbegbe Onipẹpẹyẹ, loju ọna marosẹ Abẹokuta si Ṣagamu, nibẹ niyawo si ti dagbere faye lọjọ Ẹti, ọjọ keji, oṣu keje, ọdun 2021 yii.
Awọn TRACE lo fiṣẹlẹ yii ṣọwọ sawọn akọroyin, Babatunde Akinbiyi ti i ṣe alukoro wọn si sọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ kọja iṣẹju mọkanlelogun nijamba naa waye.
O ṣalaye pe Ipẹru lawọn meji to wa ninu ọkọ naa ti n bọ, o ni tọkọ-tiyawo ni wọn, Abẹokuta ni wọn si n lọ. Akinbiyi fi kun un pe ọga nọọsi ti wọn n pe ni Matron ni iyawo yii, o ni ọsibitu jẹnẹra Ipẹru lo ti n ṣiṣẹ.
O tẹsiwaju pe idanwo ti wọn yoo fi gbe obinrin naa ga si i lẹnu iṣẹ lo fẹẹ lọọ ṣe niluu Abẹokuta laaarọ ọjọ Jimọ naa, ti ọkọ rẹ fi n gbe e lọ ninu mọto wọn ti nọmba ẹ jẹ APP 347 GF, ṣugbọn ti ere to n sa pọ ju.
Ojiji ni apa ọkọ-iyawo ko ka mọto naa mọ nigba ti ere ọhun pọ ju, nigba naa lo si kuro loju ọna, to wọgbo lọ. Bi mọto ọhun ṣe wọgbo lo run jegejege, ẹsẹkẹsẹ lagba nọọsi naa si dagbere faye, o ku patapata ni.
Ọkọ to wa mọto ko ku, oun kan ṣesẹ ni. Ọsibitu Jẹnẹra to wa n’Ijaye lo ti n gbatọju, nigba ti wọn gbe oku iyawo rẹ lọ si mọṣuari ọsibitu kan naa.
TRACE ba awọn eeyan obinrin to ku naa daro, wọn si ni awọn ko ni i yee kilọ fawọn awakọ pe ki wọn yee sare buruku loju popo, gbigbọ wọn di ọwọ Oluwa.