Iyawo mi fẹẹ fi lilu pa mi o, mi o fẹ ẹ mọ- Gbade 

Ọlawale Ajao, Ibadan

“Loootọ ni mo fọ ọkọ mi leti. Oniṣekuṣe ọkunrin ni, ọmọ kan bayii laduugbo wa lo n ba sun, nitori ẹ ni mo ṣe fọ ọ leti.”

Iyawo ile kan, Olubunmi Ọlaniyi, lo ṣe bayii sọrọ ni kootu ibilẹ Ile-Tuntun, to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja.

Ọrọ yii jẹ awijare rẹ nigba ti ọkọ ẹ, Gbade Ọlaniyi, pe e lẹjọ si kootu naa, to ni ki ile-ẹjọ fopin si igbeyawo ọlọdun mẹtala to wa laarin awọn, nitori pe iyawo oun ti fẹẹ ẹ fi lulu gbẹmi oun ninu ile.

Gẹgẹ b’ọkunrin oniṣowo naa ṣe sọ niwaju igbimọ awọn olugbẹjọ, “iyawo mi ti gba ṣokoto nidii mi, o ti sọ mi dobinrin ninu ile. Ẹnu mi ko ka a rara, igbakugba lo maa n jade bo ṣe wu u lai dagbere fun mi. Bẹẹ ni ko bọwọ fun mi rara gẹgẹ bii olori ẹbi.

“Ki nnkan kan ma ti i ṣẹlẹ laarin wa ni, aa ti sare maa gba mi leti. Koda, o fọ mi leti kan lọjọ keji, oṣu kẹjọ, ta a wa yii (lọjọ Aiku to lọ lọhun-un), o si fèèkánná ya mi loju.”

Njẹ kin niyawo ẹ fọ ọ leti si lọjọ Sannde ọhun, olupẹjọ yii fesi, o ni “ki i ṣe pe mo ṣẹ ẹ lẹṣẹ kan o, o n beere pe nibo ni mo lọ, niori pe mi o da a lohun lo ṣe fọ mi leti. Kinni yẹn si ti di gbogbo igba rẹ, a à ni i ti i sọrọ kan ti yoo ti yaa maa nawọ igbaju si mi.

Nigba ti wọn pe Olubunmi lati waa wi tẹnu ẹ, obinrin naa ko fọrọ sabẹ ahọn sọ, o ni loootọ loun fọ ọ leti, ṣugbọn ọkunrin naa ni ko jẹwọ nnkan to ṣe gan-an ti oun fi ṣe bẹẹ da sẹria fun un.

O ni, “O ti sọ mi dìdàkudà, mo ti darugbo ọsan gangan kalẹ lai ti i debi kan. Mi o laṣọ lọrun nitori ki i ṣe ojuṣe ẹ lori emi atawọn ọmọ. Ko tiẹ si aṣọ gidi kankan fawọn ọmọ yẹn lati maa wọ mọ.

“Asiko ti mo ba wa ninu oyun gan-an, ki i tọju mi. Nitori ẹ ni mo ṣe maa n jade lati wákan ṣèkan ko too febi pa oluwa ẹ sinu ile.

“Gbogbo nnkan to mọ ni ko maa ṣeranu kaakiri adugbo. Bẹẹ lo ba ọmọbinrin kan ti wọn n pe ni Shukura laduugbo wa sun. Ko mọ pe aṣiri oun ti tu si mi lọwọ nigba ti ẹgbọn ọmọ yẹn n ba a wi pe o tẹdii silẹ fun ọkọ mi, ṣugbọn nigba ti mo dele ti mo bi i leere, irọ lo bẹrẹ si i pa fun mi. Idi ti mo ṣe fọ ọ leti lọjọ Sannde niyẹn.

“Ṣaaju igba yẹn ni mo ti ri mẹseeji to fi fi kaadi ranṣẹ sọmọ yẹn lori foonu rẹ. Iyẹn ni ko jẹ ki n ṣiye meji nigba ti mo gbọ lẹnu aunti ọmọ Shukura yẹn pe ọkọ mi n ba a laṣepọ.”

Bo tilẹ jẹ pe Olubunmi ati ọkọ ẹ jọ fara mọ pe kile-ẹjọ fopin sigbeyawo awọn, igbimọ awọn adajọ kootu yii ko ṣe bẹẹ, kaka bẹẹ, niṣe ni wọn rọ wọn lati lọọ yanju ọrọ naa laarin ara wọn nile.

Oloye Henry Agbaje ti i ṣe olori igbimọ awọn adajọ naa waa sun gbẹjọ ọhun sọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ti i ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, ni ireti pe awọn ẹbi wọn yoo ti yanju gbogbo ede aiyede to wa laarin wọn.

Leave a Reply