Faith Adebọla, Eko
Ọkunrin ẹni ọdun marundinlaaadọrun-un kan, Akinọla Ikudọla, ti wọ iyawo rẹ, Funṣọ Ikudọla, rele-ẹjọ kọkọ-kọkọ to wa ni Igando, nipinlẹ Eko, o ni ki wọn ba oun fopin si igbeyawo ọdun mọkanlelogun naa.
Pataki ẹsun tọkunrin to pera ẹ loniṣowo yii ka siyawo ẹ lẹsẹ ni pe obinrin naa n yan ale, kinni ọhun si ti wọ ọ lara debii pe o loyun fun ale, bo tilẹ jẹ pe ko kuro lọdọ oun, o ṣi bimọ naa.
Ọdun to kọja lo lọrọ naa waye, o ni niṣe lo kan ṣadeede sọ foun lọjọ kan toun tibi iṣẹ de pe oun ti loyun, bẹẹ o ti pẹ gan-an toun ati ẹ ti laṣepọ kẹyin, ṣugbọn oun o wi kinni kan.
Asẹyinwa asẹyinbọ, o bimọ naa, ile lo bi i si, o taku, ko fẹẹ lọ sọsibitu, ṣugbọn ọmọ naa ku lẹyin wakati diẹ to daye.
Akinọla tun fẹsun kan iyawo ẹ pe obinrin naa n fẹwọ gidi, ki i foju kan owo oun, ọpọ igba laṣiiri ẹ si ti tu soun lọwọ. Ati pe oun lo ba igbesi aye awọn ọmọ meji to bi foun jẹ, abi-i-kọ lo ṣe awọn ọmọ ọhun, irin iranu to mọ-ọn lara lawọn ọmọ naa rawọ le. Tori ẹ, kile-ẹjọ ṣaa fopin si igbeyawo awọn, ki kaluku maa ba tirẹ lọ. O loun ko fẹ nnkan mi-in ju iyẹn lọ.
Nigba ti wọn fun iyawo naa lanfaani lati fesi si ẹsun tọkọ ẹ ka si i lẹsẹ, obinrin naa ni alagbere paraku lọkọ toun fẹ, ko si nitiju rara, latori obinrin kan si omi-in lo n faye ẹ ṣe.
Ni ti ọrọ oyun, o loun ko loyun fun ale kankan, irọ lọkọ oun pa mọ oun. O ni lọjọ to sun mọ oun toyun fi de, oun loun diidi rọ ọ lọti yo ko le ba oun laṣepọ, tori o ti n febi ibalopọ pa oun tipẹ.
Ni ti ọrọ awọn ọmọ to ya iyakuya, Funṣọ ni baba wọn lo fa a, ko nifẹẹ awọn ọmọ rẹ rara, niṣe lo n leju mọ wọn, ko si raaye kọ wọn lẹkọọ.
Wọn tun bi i pe ṣe o fara mọ ẹbẹ ọkọ rẹ lati tu igbeyawo wọn ka, obinrin naa loun fara mọ ọn, tori ajọṣe naa ti su oun pẹlu.
Lọrọ kan, Adajọ ati Aarẹ kootu naa, Ọgbẹni Adeniyi Kọledoye, ni kawọn mejeeji ṣi maa lọ na, ki wọn pada wọn lọjọ keji, oṣu keji, ọdun to n bọ, lati mọ ibi ti wọn maa fori ẹjọ ti si.