Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Se ohun to ba n dun ni ni i pọ lọrọ ẹni, ologun ẹru ku, aṣọ rẹ si jẹ ọkan ṣoṣo. Bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri fun baale ile kan, Ọmọọba Adegbemile Ọlatẹru-Ọlagbẹgi, to wọ iyawo rẹ, Abilekọ Kẹmisọla Ọlagbẹgi, lọ si kootu. Ẹsun to fi kan an ni pe o n yan ale, yatọ si pe o n yan ale, o ni ki i fun oun ni yunkẹ yunkẹ, ere akọ ati abo ṣe. Abalọ ababọ, kootu ti tu igbeyawo naa ka, wọn ni ki wọn maa lọ lọtọọtọ, ki baale ile naa le lọọ fẹ iyawo mi-in ti wọn yoo jọ maa ṣe totomẹlẹto gẹgẹ bo ṣe fẹ.
Kootu kọkọ-kọkọ to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, lo tu igbeyawo ọlọdun meje naa ka latari ọkan-o-jọkan awọn ẹsun ti ọkọ iyawo ọhun fi kan iyawo aya rẹ, Abilekọ Kẹmisọla Ọlagbẹgi.
Ni ibamu pẹlu alaye ti olupẹjọ, Ọmọọba Ọlatẹru-Ọlagbẹgi, ṣe lasiko to n rojọ, o ni iyawo oun ati iya rẹ ko fi oun lọkan balẹ rara ninu igbeyawo awọn. Baale ile naa ni lati igba toun ti gbe ọmọ rẹ niyawo ni ana oun ti bẹrẹ wahala, ti ko si jẹ kawọn fi igba kankan gbadun igbeyawo naa.
Ọmọọba niluu Ọwọ ọhun ni ọpọ igba ni oun ti kilọ fun olujẹjọ pe ko yee wọ aṣọ onihooho, ko si maa mura gẹgẹ bii ayaba, ṣugbọn ti ko gbọrọ si oun lẹnu.
O ni gbagbaagba ni iya rẹ si maa n wa lẹyin rẹ pẹlu awawi pe sokoto wiwọ ko lodi rara, nitori o ba iṣẹ ọlọpaa to n ṣe mu.
Lọjọ kan lo ni iyawo oun paaki mọto saarin ọna lasiko ti awọn n lọ si ṣọọṣi lọjọ isinmi, lẹyin to mọ pe oju to n dun oun ko le jẹ ki oun riran wa ọkọ.
O ni lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ ni olujẹjọ too pada wọnu ọkọ naa lati gbe awọn lọ si ṣọọṣi ti awọn n lọ, ọkan-o-jọkan kobakungbe ọrọ lo ni o fi sin oun de ile-ijọsin lọjọ naa.
Ọmọọba Ọlagbẹgi ni iyawo oun ti fẹran wahala ju, bẹẹ ni ki i tọju oun bo ti tọ ati bo ti yẹ.
Paripari ẹsun ti olupẹjọ fi kan iyawo rẹ ni bi ki i ṣee gba oun laaye lati ba a ni ajọṣepọ latari iṣekuṣe to n ṣe kiri. O ni asiko kan wa toun ko arun ibalopọ lati ara obinrin naa latari irinkurin rẹ.
Ọlagbẹgi ni awọn iwakiwa ti obìnrin naa n hu ti jẹ ki ifẹ rẹ yọ lọkan oun patapata, idi si ree ti oun fi wá sile-ẹjọ ki wọn le ba awọn tu igbeyawo to so awọn mejeeji pọ ka.
Ninu awijare tirẹ, olujẹjọ yii ṣẹ lori gbogbo ẹsun ti olupẹjọ fi kan an, o ni ọkọ oun ni ko ni itẹlọrun, nitori gbogbo ohun to wa ni ikawọ oun ni oun fi n ṣe itọju rẹ.
Iyaale ile yii ni oun naa fara mọ ọn ki kootu tu ibaṣepọ to wa laarin awọn ka, nitori ọpọ igba ni ọkọ oun maa n kọ awọn ọmọ to ti bi saaju si oun, awọn ọmọ ọkọ rẹ yii lo ni wọn maa n bu oun, ti wọn yoo si tun lu oun ni alubami.
O ni kile-ẹjọ tete tu awọn ka, ki wọn si gba oun laaye ki ọmọ kan ṣoṣo ti awọn bi ṣi wa nikaawọ oun fun itọju to peye.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Aarẹ kootu ọhun, Alagba Oluṣẹgun Adetiba, paṣẹ pe ki igbeyawo naa di tituka, niwọn igba ti ko ti si ifẹ mọ laarin tọkọ-taya naa.
Adetiba ni ki ọmọbìnrin to pa awọn mejeeji pọ wa ni ikawọ iya rẹ, ati pe olupẹjọ gbọdọ maa san ẹgbẹrun lọna ogun Naira loṣoosu fun itọju rẹ ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira lọdun gẹgẹ bii owo ile ti ọmọ naa yoo maa gbe.