Iyawo mi n yan ale mọ mi lara, o tun maa n foonu awọn okunrin niṣeju mi-Olubọde

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ti baale ile kan, Olubọde Benson Yéwándé, tu gbogbo aṣiri iwa buruku ọwọ iyawo ẹ, Tawakalitu Abíọ́lá Yéwándé, níwájú ọkẹ àìmọye eeyan nile-ẹjọ, igbimọ awọn adajọ kootu ibilẹ Ọja’ba, to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, ti fopin sí igbeyawo ọdun mẹwaa to wa laarin awọn mejeeji.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, lọkunrin tiṣa naa ṣalaye pe niṣe loun máa n fẹẹ lè tọ̀ sara ni gbogbo igba ti oun ba ti fi oju kan iyawo oun nileewe ti oun ti n ṣiṣẹ tiṣa. Idi ni pe gbogbo igba to ba wa bẹẹ lọ máa n yẹyẹ oun loju awọn akẹkọọ atawọn tiṣa ẹgbẹ oun.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, “O ti to ọdun mẹrin bayii ti emi pẹlú ẹ ko ti ko gbe papọ mọ. Wahala to máa n fa ni gbogbo igba naa lo jẹ ki lanlọọdu le wa jade nile ta a jọ gbe gbẹyin.

“Emi ni mo n sanwo ileewe awọn ọmọ wa mejeeji pẹlu ọmọ tó ti bi fọkunrin mi-in ko too di pe a fẹra. Bẹẹ ni mo n gbọ gbogbo bukata to yẹ kí n gbọ lori oun atawọn ọmọ yẹn.

“Ṣugbọn o ya mi lẹnu pe aṣọ ọdun Keresi ti mo ra fún awọn ọmọ lodun to koja yii, niṣe niyawo mi waa sọ aṣọ naa lu mi laya, o ni awọn ọmọ sọ pe awọn ko fẹ iru eyi ti mo ra yẹn.”

Bi Benson ṣe tú aṣọ naa han igbimọ awọn adajọ ni kootu ọhún lawọn ero to wa nile-ẹjọ bẹrẹ si kùn, wọn n rọ̀jò eebu le Abiọla lori, wọn ni aláìmoore obinrin ni, ati pe oun lo kọ awọn ọmọ naa pe ki wọn ma ṣe gba aṣọ naa.

Tiṣa to peyawo ẹ lẹjọ yii fi kun un pe obinrin naa n ṣagbere mọ oun lara, nibi to si dun mọ ọn de, a tun maa gba ipe ọkunrin mi-in niṣeju oun. O ni ọrọ kobakungbe lo máa n sọ si awọn ẹbi oun.

“Ẹgbẹrun mẹwaa naira ni mo máa n fi ranṣẹ sinu akaunti rẹ loṣooṣu pe ko máa fi jẹun. Loṣu ti mo fi ẹgbẹrun mẹfa aabọ ranṣẹ si i nitori pe ara mi ko ya nigba naa, diẹ lo ku ki iyawo mi da ori ila rú nigba to binu ko owo yẹn waa ka mi mọ sukuu.”

O waa rọ ile-ẹjọ lati fopin si igbeyawo ọdun mẹwaa to wa laarin oun ati olujẹjọ.

Leave a Reply