Iyawo mi ni irawọ awọn to wa n ṣiṣẹ iṣegun lọdọ mi ni mo n lo, mi o fẹ ẹ mọ-Gbolagade

Jide Alabi

Ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa ni Ile-Tuntun, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ti tu igbeyawo ọdun mẹta ka laarin ọkunrin oniṣegun ibilẹ kan, Iṣọla Gbọlagade ati iyawo ẹ, Yetunde.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni ituka ọhun waye laarin Gbọlagade, ẹni ti wọn pe loniṣegun ibilẹ, ati Yetunde. Ẹsun ti ọkọ yii fi kan iyawo ẹ ni pe niṣe lo n rojọ oun kiri ilu Ibadan, to n pe oun ni oṣo to n lo irawọ awọn to waa ṣiṣẹ iṣegun lọdọ ẹ fi sowo loun.

Gbọlagade tun fi kun un pe, obinrin naa ko bimọ kankan foun, bẹẹ lo n fi ọrọ ibajẹ le awọn onibaara lọdọ oun pẹlu ọrọ buruku to n sọ nipa oun kiri.

“Orukọ buruku lobinrin yii ti sọ mi laarin ilu, niṣe lo n rojọ mi kiri pe irawọ awọn to n waa ṣiṣẹ iwosan lọdọ mi ni mo n lo, ti mo fi n ṣiṣẹ ọla funra mi, emi o ri iru Yetunde yii ri o, fun idi eyi, mi o fẹ ẹ mọ, ki kaluku maa ba tiẹ lọ. Nitori ti ko ba kuro lọdẹdẹ mi, o lewu o, mi o si fẹẹ lokuu eeyan kankan lọrun, oun gan-an ti sọ pe oun loun maa pa mi tẹlẹ.”

Yetunde ni tiẹ naa ko jiyan si gbogbo ohun ti ọkọ ẹ ka silẹ yii, niṣe lo tẹnumọ ọn pe ika ati ọdaju lọkunrin naa n ṣe, to si maa n ko wahala ba oun lọpọ igba.

Aarẹ ile-ẹjọ naa, Oloye Henry Agbaje, sọ pe ko si ohun ti oun le ṣe sọrọ awọn mejeeji, paapaa bi wọn ṣe fariga pe awọn ko fẹẹ jọ wa papọ mọ gẹgẹ bii lọkọ-laya.

Ninu idajọ ẹ naa lo ti sọ pe Gbọlagade gbọdọ maa fun Yetunde ni ẹgbẹrun meje aabọ naira lati maa fi sanwo ile.

Leave a Reply