Iyawo mi ti sọ ara ẹ di aja, tẹnanti ẹgbẹ mi lo n ba a laṣepọ- Kazeem

Ọlawale Aajao, Ibadan

Igbeyawo ogun ọdun to wa laarin tọkọ-tiyawo kan, Kazeem Hamzat ati Mujidat Hamzat, ti fori ṣanpọn, ọkọ lo fariga pe oun ko ṣe mọ, o ni anfaani adugbo niyawo oun, gbogbo ọkunrin adugbo lo ti fẹẹ ba a laṣepọ tan.

Nigba to n rọ ile-ẹjọ ibilẹ Ọja’ba, to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, lati tu igbeyawo ọhun ka l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, Kazeem to pera ẹ lolugbe adugbo Odo-Ọba, n’Ibadan, sọ pe “Mo ti ka ọkunrin mọ ori iyawo mi ri, aimọye igba ni wọn si ti n ṣeṣekuṣe bẹẹ ki n too ka wọn mọ.

“Nnkan to kọkọ ya mi lẹnu ni pe bi mo ṣe tibi iṣẹ de lọjọ kan lo yari pe afi dandan ki n tun rẹnti yara ofifo kan to wa ninu ile wa. Aṣe nitori ko le maa raaye ṣeṣekuṣe ni.

“Loru ọjọ kan ni mo wa a tì lẹgbẹẹ mi lori bẹẹdi. Mo lọọ wo o ni yara keji ta a rẹnti niṣalẹ, mi o ba a nibẹ. Nigba ti mo pada si yara ni mo bẹrẹ si i gbọ ohùn bẹẹdi ọkunrin àpọ́n ti yara ẹ wa lẹgbẹẹ yara wa nitori bẹẹdi onírin lo n lo. Mi o gbọ ohun iyawo mi, ṣugbọn ọkan mi sọ fun mi pe iyawo mi lọkunrin yẹn n ba sun nitori ìró bẹẹdi yẹn ko jọ tẹni to n jarunpá, bii igba ti wọn n laṣepọ lori ẹ ni.

 

“Mo lọọ kanlẹkun yara yẹn, ṣugbọn ẹnikankan ko dahun. Mo kanlẹkun kanlẹkun, wọn ko ṣilẹkun. Ariwo ilẹkun ti mo n kan ati ariwo ti mo n pa lawọn araale gbọ ti wọn fi jade si mi, aimọye igba lawọn naa gba ilẹkun, ṣugbọn sibẹ, ọkunrin yii ko ṣilẹkun. Wọn waa parọwa fun mi pe ki n fi wọn silẹ ki n lọọ sun, ki n fọrọ m’Ọlọrun.

“Mo ro pe inu fiimu nikan niru iṣẹlẹ bẹẹ ti maa n waye ni, igba to ṣẹlẹ si mi yii ni mo too mọ pe aye n ṣeru ẹ loootọ.

Ko ju ọjọ karun-un lọ ti iyawo mi lọọ sun ti ọkunrin yẹn ni yara ẹ niru iṣẹlẹ yẹn tun waye. Njẹ ẹ mọ pe niṣe niyawo mi n fi mi ṣe yẹyẹ lati fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni nnkan wa laarin oun pẹlu alabaagbe wa.

Ọrọ yẹn dìja gidi laaarọ ọjọ keji. Wahala yẹn lo jẹ ki lanlọọdu fun wa niwee pe ka jade kuro ninu ile oun. Ṣugbọn o dun mi pe ẹyin iyawo mi ni lanlọọdu maa n wa lori gbogbo iwa palapala to maa n hu. Njẹ ẹ jẹ mọ pe emi nikan ni mo kuro nibẹ, inu ile yẹn niyawo mi ṣi n gbe di bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii.”

 

Ni ibamu pẹlu ibeere igbimọ awọn adajọ, Kazeem ṣalaye pe oun naa lo fẹnu ara ẹ sọ ọ. ‘‘Nigba ti mo n ba a ja laaarọ ọjọ keji to lọọ sun ti alabaagbe wa, isọkusọ lo n sọ lẹnu, o ni ẹ jẹ ma para yin nitori ẹni ti ko le ta putu.

“Mo ni bawo lo ṣe mọ pe ko le ta putu, o ni iya ẹ lo sọ foun pe ọmọ oun ko le ṣe. Ta a ba wo ọrọ yii daadaa, Oluwa mi, ẹ ẹ ri i pe iyawo mi ati ọkunrin yẹn ti wọwọ́ ju bo ṣe ye lọ, abi ki loun atiya ọkunrin yẹn le sọ debii pe ọmọ rẹ ko le ṣe.

“Mo rọ ile-ẹjọ yii lati tu igbeyawo wa ka, kẹ ẹ si yọnda awọn ọmọ wa meejeji fun mi nitori obinrin yii ko raaye ọrọ ọmọ kankan.”

Ọga awọn adajọ kootu naa, Oloye Ọdunlade Ademọla, beere bi Mujidat ṣe mọ pe òkóbó lọkunrin alabaagbe wọn naa, o si fidi ẹ mulẹ pe iya ọkunrin naa lo tu aṣiri ẹ foun gẹgẹ bi ọkọ ẹ ti ṣe sọ ṣaaju.

Olujẹjọ ta ko ẹsun agbere ti ọkọ ẹ fi kan an, o loun ko ni ibalopọ pẹlu ọkunrin mi-in ri lẹyin ọkọ oun.

“Ọdaju ọkunrin ni Kazeem bẹ ẹ ṣe n wo o yẹn, ko jẹrii mi rara. Aimọye igba lo ti le mi ni mágùn nitori o ro pe mo n yan ale, emi o si lọkunrin mi-in lẹyin ẹ̀ ni temi”, bẹẹ lobinrin to pera ẹ loniṣowo naa sọ niwaju igbimọ awọn adajọ.

Ile-ẹjọ ti fopin si igbeyawo ogun ọdun to seso ọmọ meji naa, wọn si yọnda awọn ọmọ naa fun olujẹjọ lati maa tọju.

“Oloye Ọdunlade ati igbimọ ẹ, iyẹn Alhaji Suleiman Apanpa ati Alhaji Rafiu Raji pa olupẹjọ laṣẹ lati maa san ẹgbẹrun mẹfa (N6,000) fun olujẹjọ gẹgẹ bii owo itọju awọn ọmọ wọn mejeeji ti ile-ẹjọ yọnda fun iya wọn lati maa tọju.

Bakan naa ni wọn pa Kazeem laṣẹ lati fun obinrin naa lowo ti yoo fi ko ẹru rẹ jade lọ sibikibi to ba fẹ ninu igboro Ibadan.

 

Leave a Reply