Iyawo olori ileegbimọ aṣofin Ọṣun tẹlẹ, Najeem Salaam, ti ku o

Florence Babaṣọla

Olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọnarebu Najeem Salam, ti kede iku ọkan lara awọn iyawo rẹ, Adebimpe Adukẹ Salam, eyi to ṣẹlẹ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ninu ọrọ to fi sori ayelujara laipẹ yii ni ọkunrin oloṣelu ọmọ bibi ilu Ejigbo naa ti sọ pe oun ko le bi Ọlọrun lẹjọ lori adanu nla naa, ṣugbọn oun ti gba bi akọsilẹ oun ṣe ri.

Oṣogbo la gbọ pe obinrin ẹni to ti to aadọta ọdun naa ku si laaarọ oni lẹyin aisan ranpẹ.

Oun niyawo keji fun Salam, ileewosan ijọba to wa niluu Ejigbo lo si ti n ṣiṣẹ nitori oṣiṣẹ eleto ilera ni. Irọlẹ ọjọ Aje ọsẹ yii la gbọ pe wọn yoo si sinku rẹ nilana Musulumi nile wọn to wa niluu Ejigbo.

Latigba ti ọkọ rẹ ti kede iku ọhun lawọn araalu, paapaa awọn oloṣelu ti n ranṣẹ ibanikẹdun si i.

Gomina Oyetọla ṣapejuwe obinrin naa gẹgẹ bii onirẹlẹ to fọwọ ti ọkọ rẹ lẹyin, to si jẹ apẹẹrẹ rere fun awọn obinrin ti ọkọ wọn n ṣoṣelu.

 

Leave a Reply