Ọmọbinrin kan, Rahma Hussein, ko ju ọmọ ọdun mẹrindinlogun (16) lọ lọdun 2014 ti wọn fa a fun ọkọ niluu wọn nipinlẹ Kano. Ọjọ kan lẹyin to wọle ọkọ ọhun lo si gun un lọbẹ pa. Ohun to gbe e de ẹwọn ree, ki wọn too tu u silẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii.
Igbimọ to n ri si atunṣe ọgba ẹwọn, eyi ti Adajọ Ishaq Bello jẹ ọga fun lo ṣeto bi wọn ṣe yọnda ọmọbinrin yii pẹlu awọn ẹlẹwọn ọgbọn mi-in ti wọn tun fi oju aanu wo.
Ile-ẹjọ giga ni wọn ti dajọ ọmọbinrin yii nigba naa, Adajọ si paṣẹ pe ki wọn da a duro sọgba ẹwọn na, nitori ọjọ ori rẹ ṣi kere, ati pe wọn fipa mu un lati fẹ ọkọ to fẹ naa ni.
Nigba to n ṣalaye idi ti wọn fi yọnda Rahma to ti pe ọdun mẹtalelogun bayii, Alukoro ọgba ẹwọn naa ni Kano, Musbau Kofar Nassarawa, sọ pe bi wọn ṣe fi i silẹ ko ṣẹyin ohun ti awọn alaboojuto ẹwọn naa sọ nipa ọmọ yii.
O ni wọn fidi ẹ mulẹ pe iwa rẹ ti yipada gidi latigba to ti wa lahaamọ, bẹẹ lo si ni akikanju iṣẹ, o mọ bi wọn ṣe n fi ookan kun eeji ti kinni ọhun yoo si so eeso rere.
Alukoro ṣalaye pe igbimọ to n ri si ọrọ ọgba ẹwọn naa tun ba Gomina Abdullahi Ganduje sọrọ, pe ko wo ti pe agidi ni wọn fi mu ọmọde naa fẹ ẹni ti ko wu u, eyi to le jẹ idi pataki to fi ṣe aṣiṣe, to si gun ọkunrin naa pa. Wọn ni ki Gomina dariji i, oun si gba, ni wọn ba da a silẹ lẹyin ọdun meje ni gbaga.
Nigba to n fomije dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti wọn ṣaanu rẹ ti ominira fi de fun un yii, Rahma loun tun gba a laduura fun wọn pe awọn naa yoo ri aanu gba, Ọlọrun yoo si san wọn lẹsan ire.