Jacob ati ọrẹ ẹ yoo pẹ lẹwọn o, adiẹ ni wọn lọọ ji ko n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ Magistreeti kan to wa niluu Ilọrin ti paṣẹ pe ki wọn ju Jacob Peter ati ọrẹ rẹ, Baba Ochi, sẹwọn fẹsun pe wọn lọọ ji adiẹ to din diẹ lẹẹẹdẹgbẹta (450), ko ninu oko oloko ni Lasoju, Ilọrin, ipinlẹ Kwara.
Agbefọba, Insipẹkitọ Iwaloye AbdulRauf, sọ fun kootu pe lọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ni ọwọ fijilante tẹ awọn afurasi ole mejeeji nibi ti wọn ti n ji adiẹ ko ni Abule kan ti wọn n pe ni Lasoju, ti Yusuf Samuel to jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ fijilante si fa awọn afurasi ọhun le ọlọpaa lọwọ.
O tẹsiwaju pe adiẹ ti wọn ji to miliọnu kan aabọ niye (N1.5 million). Peter jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, ati pe oun ko le sọ iye adiẹ toun ti ji ninu oko naa, ti awọn aa si se e jẹ. Ṣugbọn Ochi ni ohun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun tori pe oun ki i tẹle Peter lọọ ji adiẹ, ṣugbọn loootọ lawọn jọ maa n jẹ ẹ to ba ti ji i tan.
Adajọ Moshood Ajibade paṣẹ pe ki wọn lọọ sọ Peter sẹwọn. O gba beeli Ochi pẹlu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira (N300,000), pẹlu ẹlẹrii meji tawọn naa yoo san iye owo naa.
O ni ki o wa lahaamọ titi yoo fi ri owo beeli ati ẹlẹrii meji san.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ karun-un, oṣu Keje, ọdun yii.

Leave a Reply