Jala epo bẹntiroolu yoo di ojilelọọọdunrun naira (N340) lọdun to n bọ o-Ijọba

Faith Adebọla

Nigba to ba fi maa di oṣu keji, ọdun to n bọ, iye owo ti wọn maa maa ta jala epo bẹntiroolu ti wọn n pe ni PMS (Premius Motor Spirit) yoo lọ soke si ojilelọọọdunrun naira (N340) tabi ko din diẹ.

Mallam Mele Kyari, Ọga agba ajọ to n dari wiwa epo rọbi nilẹ wa, Nigerian National Petroleum Company (NNPC), lo sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, niluu Abuja.

Nigba to n sọrọ nibi apero atigbadegba kan lori eto idagbasoke orileede ti Ajọ banki agbaye (World Bank) gbe kalẹ, Kyari ni ofin ilẹ wa ko faaye gba eto kijọba maa fi owo kun iye to yẹ ki wọn maa ta epo faraalu, eyi ti wọn n pe ni subsidy, o ni ilana subsidy ko bofin mu rara, ijọba si maa jawọ ninu afikun owo naa loṣu keji, 2022.

O ni tijọba o ba san afikun owo mọ, iye tawọn eeyan aa maa ra epo bẹntiroolu yoo wa laarin okoolelọọọdunrun naira (N320) si ojilelọọọdunrun naira (N340).

O nijọba ti n wo nnkan ti wọn maa ṣe lati ma ṣe jẹ ki ara ni araalu ju bo ṣe yẹ lọ, bo tilẹ jẹ pe igbesẹ naa ko ṣee da duro mọ.

Bakan naa ni Kyari sọ pe ọwọngogo afẹfẹ gaasi lasiko yii ki i ṣe ẹbi ijọba rara, o nijọba ko fowo kun owo gaasi, ṣugbọn bi ilo afẹfẹ naa ṣe tubọ n lọ soke si i kari aye lo mu kowo rẹ maa ga si i, eyi ki i ṣe ọrọ orileede wa nikan, kari aye ni.

O ni ileeṣẹ NNPC ti n ṣiṣẹ lori bi wọn ṣe maa maa pese afẹfẹ idana to pọ to labẹle wa, fun irọrun araalu, laipẹ.

Leave a Reply