Ninu ọgba ileewe ni Jamiu ti fipa ba akẹkọọ lo pọ n’Ilese-Ijẹbu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ẹka ti wọn ti n mojuto akọsilẹ iwe awọn akẹkọọ nileewe ẹkọ nipa ilera (College of Health Technology) to wa ni Ilese-Ijẹbu, ni ọkunrin yii, Ọlawale Jamiu, ti n ṣiṣẹ, ibẹ naa lo ti ki akẹkọọ-binrin to fẹẹ gba iwe lọwọ ẹ mọlẹ, to si fipa ba a lo pọ karakara.

Awọn alaṣẹ ileewe naa ni wọn lọọ sọrọ Jamiu, ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) fun wọn ni teṣan ọlọpaa Ilese, iyẹn lẹyin ti ọmọ to fipa ṣe kinni fun ṣalaye fun alagbatọ ẹ nile pe faili ileewe loun lọọ gba lọwọ oṣiṣẹ ibẹ yii to fi run oun mọnu yara ikowee-si, to si fipa ba oun sun gidi gan-an. Alagbatọ rẹ lo lọọ ṣalaye fawọn alaṣẹ ileewe yii, ti wọn fi pada lọọ fi to ọlọpaa leti.

Awọn ọlọpaa gba ileewe naa lọ, wọn mu afurasi yii, ṣugbọn niṣe lo sẹ kanlẹ pe oun ko dan palapala bẹẹ wo, o ni irọ lọmọbinrin naa pa mọ oun.

Nibi ti Jamiu ti n jiyan lawọn ọlọpaa ti fi atẹjiṣẹ to fi ranṣẹ sori foonu ọmọ naa han an, nibi to ti bẹ ọmọbinrin yii pe ko ma binu nipa ohun toun ṣe fun un, to ni ko foriji oun pe oun fipa ko ibasun fun un.

Nigba to ri atẹjiṣẹ to fọwọ ara ẹ fi ṣọwọ naa lara rẹ balẹ, ko si le purọ kankan mọ.

Wọn gbe ọmọ to ba sun lọ sọsibitu ijọba to wa n’Ijẹbu-Ode, fun itọju, wọn si gbe Jamiu lọ sẹka to n ri si ẹsun to jẹbi rẹ yii, ibẹ ni yoo gba dele-ẹjọ.

Leave a Reply