Jan-mọ-ọn mọṣalaaṣi ti mo ti n kirun fun wọn fun iyawo mi loyun-Alaaji Shittu

Ọlawale Ajao, Ibadan

Imaamu mọṣalaaṣi kan niluu Ọyọ, Alaaji Lukman Shittu, ti fẹsun kan ọkan ninu awọn janmọ-ọn to n kirun ni mọṣalaaṣi to ti n kirun fun wọn pe o n ba iyawo oun lo pọ, o si ti loyun fun un.

Ilẹ-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa ni Mapo, niluu Ibadan, lo ti sọrọ naa di mimọ niwaju Onidaajọ S.M. Akintayọ. Ọkunrin naa sọ pe ohun to fa wahala laarin awọn ni bi obinrin naa ṣe ni ki oun ba oun wa owo ki oun le gba ṣọọbu, ṣugbọn ti oun ko ri owo naa fun un. O ni latigba naa lo ti n rin irinkurin, to jẹ pe alẹ patapata lo maa n wọle.

Nigba ti oun si binu si iwa to n hu yii, pẹlu ikilọ pe to ba tun ṣe bẹẹ, oun maa ti i mọta lo binu ko ẹru rẹ jade, to si ko awọn ọmọ mẹta to bi fun oun lọ pẹlu.

O fi kun un pe iyawo oun paarọ ileewe abigbẹyin awọn lai sọ fun oun, bẹẹ lo si ti gbin oro buruku si awọn ọmọ oun ninu debii pe awọn ọmọ naa ni awọn ko ni i mọ oun gẹgẹ bii baba wọn.

Aafaa yii ni,’’Lasiko Ramadan to kọja, mo ni ki ọkan ninu awọn ọmọ mi yii wa sọdọ mi, ṣugbọn ko da mi lohun. Njẹ ẹ jẹ mọ pe gbogbo igba ti awọn ọmọ naa ba wa lọlude, wọn o ki i de ọdọ mi. Eyi to si dun mi ju ninu ọrọ yii ni pe ọmọ inu mọṣalaaṣi ti mo ti n kirun fun wọn ni ọkunrin to gba iyawo mi yii.’’

‘‘Ọdun 2021 lo ko jade nile mi, ko si pẹ si asiko naa rara ti mo fi ri i to n gun ọkọ ayọkẹlẹ kiri.

Ohun to n ṣọ fun gbogbo eeyan ni pe mọlẹbi oun kan lo fun oun ni mọto naa, ṣugbọn iwadii ti mo ṣe pada fi han pe ale rẹ to n gbe e kiri naa lo gbe mọto si i nidii.’’

Ninu awijare iyawo aafaa yii, oun naa fẹsun kan ọkọ rẹ, o ni lagbere paraku ni, o ni oriṣiiriṣii obinrin lo maa n gbe wa sinu ile awọn, ko si fẹ ki oun ṣiṣẹ kankan rara.

Iyaale ile naa sọ pe ọkọ oun ti figba kan ba ṣọọbu ti oun gba, toun si raja si jẹ, nitori ko fẹ ki oun ṣiṣẹ kankan. Bẹẹ lo ni oriṣiiriṣii orukọ ti ko daa lo maa n pe oun.

O ni loootọ ni awọn mọlẹbi awọn ti da sọrọ naa, ṣugbọn oun kuro nile ọkunrin naa ki alaafia le jọba.

Adajọ ile-ẹjọ naa, S.M. Akintayọ, ni ki tọkọ-tiyawo naa lọọ ṣe ayẹwo ẹjẹ lati fidi ẹni to ni awọn ọmọ mẹtẹẹta to bi fun ọkunrin naa mulẹ. Ayẹwo yii lo ni tọkọ-tiyawo naa maa dawo jọ ṣe e ni. Bẹẹ lo ni taara ni ki ọsibitu ti wọn ba ti ṣe e mu esi ayẹwo naa wa sọdọ akọwe kootu.

Ọjọ keji, oṣu Karun-un, ọdun yii, lo ni awọn yoo yẹ esi ayẹwo ọsibitu naa wo. Lẹyin eyi ni igbẹjọ yoo ṣẹṣẹ maa tẹsiwaju.

 

Leave a Reply