Janduku mẹfa ko sakolo ọlọpaa l’Ebute Mẹta

Faith Adebọla, Eko

Teṣan ọlọpaa to wa l’Ebute Mẹta lawọn janduku kan, Qudus Ọkẹ, ẹni ọdun mejilelogun; Godwin Joseph ati Abdullahi Ajọsẹ tawọn mejeeji jẹ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, Kayi Ajayi, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, Micheal Ben, toun jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ati Oluwaṣẹgun Akinlade, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn pere, tọwọ tẹ laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, wa bayii. Ẹsun pe wọn n da omi alaafia agbegbe Ebute Mẹta, nipinlẹ Eko, ru, lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn fi kan wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko to sọ nipa iṣẹlẹ yii fun ALAROYE sọ pe ojiji lawọn bẹrẹ si i gba ipe loriṣiiriṣii ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ Iṣẹgun ọhun pe awọn janduku ẹda yii ti ya bo agbegbe ọhun, ti wọn si bẹrẹ si i lu gbogbo gilaasi mọto tawọn ẹni ẹlẹni paaki saduugbo wọn fọ, wọn ba awọn dukia jẹ, wọn si tun ja wọn lole.

O ni lẹsẹkẹsẹ lawọn ọlọpaa ti balẹ saduugbo naa, ṣugbọn awọn ẹlẹgiri yii ti fi oru boju sa lọ. Sibẹ, lẹyin ifimu finlẹ, awọn ọlọpaa ri awọn mẹfa lara wọn nigba tilẹ ọjọ keji mọ, wọn si ti n ka boroboro fawọn ọtẹlẹmuyẹ to n ṣiṣẹ iwadii lọwọ.

Adejọbi fi kun un pe awọn ṣi n wa awọn ẹlẹgbẹ wọn to ku ti wọn darukọ pe awọn jọ huwa laabi ọhun ni.

O ni awọn ti pampẹ ofin ti gbe yii yoo lọọ wi tẹnu wọn niwaju adajọ laipẹ, tiṣẹ iwadii ba ti pari.

Leave a Reply