Janduku mejidinlọgbọn dero ahamọ ọlọpaa l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 Awọn ọmọ ganfe ti wọn n daamu awọn araalu lagbegbe Agọ-Ọkọta, l’Ekoo, gbalejo awọn agbofinro ti wọn ṣabẹwo si awọn ile pako ti wọn fi ṣebugbe ti wọn n pe ni ‘Abẹtẹ’ awọn,  mejidinlọgbọn lara wọn si dero ahamọ lafẹmọju Ọjọruu, Wẹsidee, yii.

Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, lo paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ pe ki wọn ma ṣe duro de igba tawọn ọmọ iṣọta atawọn ẹlẹgbẹ okunkun yoo jade ṣọṣẹ ki wọn too maa lepa wọn mọ, o ni gbogbo ibuba wọn, ibugbe wọn ati ‘abẹtẹ’ ti wọn ba fura pe wọn n lugọ si ni ki wọn ti maa fin wọn jade bii okete.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Adekunle Ajiṣebutu, to fọrọ yii to ALAROYE leti sọ pe bawọn agbofinro ṣe de adugbo ile pako tawọn ẹruuku naa n gbe, niṣe ni gbogbo wọn bẹrẹ si i tu jade fokifoki, awọn kan lara wọn gba oju windo sa lọ, ṣugbọn awọn ọlọpaa naa gba fi ya wọn, lọwọ fi ba mejidinlọgbọn lara wọn.

Lẹyin naa lawọn ọlọpaa wo awọn ile pako wọn lulẹ, wọn si ko gbogbo panduku wọn sita, lati le wọn tefetefe.

Wọn ni Kọmiṣanna ọlọpaa Eko ti paṣẹ pe ki wọn taari awọn tọwọ ba yii si ẹka ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, ibẹ ni wọn ti maa ṣewadii wọn daadaa, ki wọn too pinnu igbesẹ to kan nipa wọn.

Leave a Reply