Jẹgẹdẹ bẹrẹ ipolongo ibo l’Akurẹ, o loun ni kawọn araalu dibo fun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Ọgọọrọ ero lo pe jọ sinu ọgba Dẹmokiresi MKO Abiọla to wa lagbegbe Ọja Ọba, l’Akurẹ, lasiko ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, n ṣe ifilọlẹ eto ipolongo ibo rẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, to kọkọ sọrọ nibi ayẹyẹ ifilọlẹ ọhun rọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo lati fi ibo wọn gbe Jẹgẹdẹ wọle ninu eto idibo to n bọ lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun ta a wa yii.

O ni oun gbọ tawọn to waa polongo fun Akeredolu n pariwo pe kawọn eeyan dibo fun ẹgbẹ APC ki ipo aarẹ baa le wa silẹ Yoruba lọdun 2023, ṣugbọn o ni irọ gbuu leyi, tori eto idibo sipo gomina ipinlẹ Ondo ko ni nnkan kan i ṣe pẹlu ipo aarẹ ilẹ Yoruba.

Makinde bẹ awọn eeyan lati dibo fun Jẹgẹdẹ ti i ṣe oludije labẹ asia ẹgbẹ PDP, ki ipinlẹ Ondo naa le darapọ mọ awọn ipinlẹ to n ja fun ṣiṣe atunto orilẹ-ede yii.

O ni kawọn eeyan ma ṣe bẹru agbara tijọba apapọ le fẹẹ lo lasiko eto idibo ọhun nitori pe ẹgbẹ APC lo wa lori aleefa l’Abuja. O ni niwọn igba toun lu ẹgbẹ wọn lalubolẹ nipinlẹ Ọyọ ninu eto idibo gbogbogboo ọdun to kọja, ko le ṣoro o ṣe fawọn naa.

Makinde ni eto idibo yii ṣe pataki pupọ sawọn eeyan, o rọ wọn lati lo anfaani rẹ lati gba ara wọn lọwọ ilo ẹru ti ẹgbẹ APC n lo wọn.

Alaga pata fun ẹgbẹ PDP, Uche Secondus, ni Aarẹ Buhari gbọdọ ri i daju pe oun ṣeto idibo ti ko lọwọ eru ninu nipinlẹ Ondo ati Edo.  O ni ki ẹgbẹ APC maa reti ibinu gbigbona Ọlọrun ti wọn ba fi dabaa ati ṣe ojooro ninu eto idibo naa.

Alaga yii ni kawọn eeyan ipinlẹ naa gbiyanju lati fi ibo wọn le Akeredolu pada sibi to ti wa lọjọ kẹwaa, oṣu to n bọ.

Jẹgẹdẹ ninu ọrọ apilẹkọ to ka lẹyin to gba asia ẹgbẹ lọwọ alaga ẹgbẹ tan ni ẹgbẹ APC ti gba iwe gbele-ẹ latari inira nla ti iṣejọba wọn mu ba awọn araalu.

Lara awọn to wa nibi ifilọlẹ yii ni, Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwa, Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri, Onimọ-ẹrọ Sẹgun Oni, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla atawọn eeyan nla mi-in ninu ẹgbẹ PDP.

Leave a Reply