Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, lọwọ ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, tẹ ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Abdulwasiu Sulaiman, lagbegbe Oke-Foma Phase 3, ile olowo pọọku ijọba apapọ, niluu Ilọrin, lasiko to lọọ ji jẹnẹretọ gbe to n dari bọ wale.
Titi di asiko ta a n ko iroyin yii jọ, ahamọ ajọ NSCDC, ni Wasiu ṣi wa latari ẹsun idigunjale ti wọn fi kan an ọhun.
Agbẹnusọ ajọ naa, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, sọ pe awọn fijilante ni wọn gba Wasiu mu lagbegbe Oke-Foma, pẹlu jẹnẹretọ aladuugbo wọn kan to n jẹ Moshood Otubu, to lọọ ji gbe. Afọlabi tẹsiwaju pe, niṣe ni Wasiu fo fẹnsi wọle, to si lọọ ji ẹrọ amunawa to to ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira gbe. Afurasi ọdaran ọhun jẹwọ pe loootọ loun ji i gbe, ṣugbọn awọn pọ ti awọn jọ n digunjale ni agbegbe naa.
Afọlabi ni iwadii n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ ọhun, ajọ naa yoo si sa ipa rẹ lati mu awọn ọdaran ẹgbẹ rẹ yooku. Ṣugbọn titi igba naa, ki Wasiu maa gba afẹfẹ lahaamọ.