Jẹnẹretọ kootu ni Fọlọrunṣọ fẹẹ ji gba tọwọ fi ba a Ado-Odo

Faith Adebọla

Yooba bọ, wọn ni Fọlọrunṣọ kan o gbọdọ fokun ọgẹdẹ gun ọpẹ, amọ ọrọ ko ri bẹẹ fun ọmọkunrin ti wọn porukọ ẹ ni Fọlọrunṣọ Ọlaniyan yii, nitori ki i ṣe pe o fokun ọgẹdẹ gun ọpẹ nikan, ọmọkunrin naa n rin ni bebe ẹwọn, o si laya pẹlu bi wọn ṣe ni ẹrọ amunawa ti wọn n lo nile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan l’Ado-Odo, nijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta, lo n gbiyanju lati ji gbe, ki wọn too ka a mọbẹ, ti wọn si mu un.

Alaroye gbọ pe ole jija ki i ṣe akọsẹba fun afurasi yii rara, wọn lo diidi mu un bii iṣẹ ni, tori lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni ọdun yii, lo yọ kẹlẹ wọnu ọgba sẹkiteria ijọba ibilẹ ti kootu naa wa, o kuku ti mọ pe ọlude wa lọjọ naa, awọn oṣiṣẹ ko ni i si i lọfiisi, tori ijọba ipinlẹ Ogun ti kede pe kawọn oṣiṣẹ ọba lọọ fi ọjọ naa gba kaadi idibo alalopẹ wọn.

Wọn ni taara lọkunrin yii lọ sinu yara ikẹrusi ti wọn maa n tọju jẹnẹretọ kootu naa pamọ si, o yọ irinṣẹ ti wọn fi n tu kọkọrọ to wa lapo ẹ jade, o si tu kọkọrọ ilẹkun naa, lo ba wọle.

Nibi to ti n ṣe kirakita lati wọ jẹnẹretọ naa, laimọ pe Ọgbẹni Tolulọpẹ Kareem, to jẹ Akọwe kootu naa wa nitosi, tiyẹn ni koun sare waa mu nnkan kan lọfiisi lọjọ naa, lo ba ka a mọbẹ.

Kia ni Tolulọpẹ ti kigbe ole le e lori, awọn ọlọdẹ to n ṣọ ọgba ọhun si gba a mu, lọrọ ba di tọlọpaa.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ kansu naa, Mercy Ajewọle, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ni loootọ lọwọ ba afurasi yii, ati pe o ti jẹwọ pe niṣe loun fo fẹnsi wọle, o ni ki wọn ṣaanu oun, ki wọn foriji oun.

Lara irinṣẹ ole ti wọn ba ninu baagi kelebe to gbe dani ni oriṣiiriṣii awọn irinṣẹ ti wọn fi n tu ẹrọ ti wọn n pe ni screwdrivers, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, jẹrii si iṣẹlẹ yii, o lawọn ọlọpaa ti n ṣewadii nipa ẹ.

Leave a Reply