Jiipu Lexus bọginni ni Samuel ati Joshua n gun kiri l’Ekoo, aṣe adigunjale ati ẹlẹgbẹ okunkun ni wọn

Faith Adebọla, Eko

Meji ninu awọn adigunjale ti ko jẹ kawọn eeyan sun oorun asundọkan l’Ekoo, Samuel Akabueze, ẹni ọdun mọkanlelogun, ati Joshua Onuoha, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, ti bọ sakolo ọlọpa. Awọn ọlọpaa ikọ ayara-bii-aṣa RRS (Rapid Response Squard) lo mu wọn lọjọ Aje, Mọnde, pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn ji gbe.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, CSP Adekunle Ajisebutu, sọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lori ikanni Wasaapu rẹ pe ẹnu iṣẹ patiroolu tawọn ọlọpaa n ṣe lọwọ laduugbo Akowọnjọ si Dọpẹmu, nijọba ibilẹ Alimọṣọ, ni wọn ti pade awọn afurasi ọdaran mejeeji, ọkọ jiipu Lexus bọginni ni wọn n wa niwakuwa kiri tawọn ọlọpaa naa fi fura si wọn, ni wọn ba tẹle wọn, agbegbe Ẹgbẹda ni wọn ti le wọn ba, ibẹ lọwọ ti tẹ wọn. Nọmba jiipu ọhun ni LAGOS LSD 666 GK.

Nigba ti wọn beere iwe ọkọ wọn lati fihan boya awọn ni wọn ni in loootọ, katikati ni wọn n sọ, ọrọ wọn ko dọgba rara, ko si pẹ ti ọkan ninu wọn fi gbiyanju lati fere ge e, lawọn ọlọpaa ba gba wọn mu.

Ni teṣan wọn, Joshua jẹwọ pe Ojule kejidinlaaadọta, Opopona Yusuf, n’Ipaja, loun n gbe, Ojule kẹrinlelogun, Opopona Valentine Obasi, ni ọna Idimu ni Samuel pe ibugbe tiẹ, lawọn ọlọpaa ba tẹle ọkọọkan wọn lọ sile lati lọọ ṣayẹwo wọn.

Adekunle ni awọn ẹsibiiti tawọn ọlọpaa ka mọ wọn lọwọ ni ibon oyinbo meji, ọta ibọn ti wọn o ti i yin rẹpẹtẹ, kaadi ATM banki Eco ati Access mẹrin, kaadi iwọkọ BRT, oogun abẹnugọngọ loriṣiiriṣii, wọn tun ri kọkọrọ ọkọ jiipu Lexus mi-in to yatọ si eyi ti wọn n gun kiri, ati kọkọrọ ọkada kan, bo tilẹ jẹ pe wọn o ri awọn ọkọ ati ọkada naa.

Ninu iwadii tawọn ọlọpaa ṣe, wọn lawọn afurasi naa jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Aiye’ lawọn, wọn ni latigba tawọn ti wa nileewe lawọn ti n ṣẹgbẹ imulẹ.

Wọn tun jẹwọ pe loootọ lawọn n digunjale, ṣugbọn agbegbe Festac, Gowon Estate, Lẹkki si Ajah, lawọn ti n ṣe ọpureṣan awọn, ibẹ ni wọn ti n pa wọn eeyan lẹkun.

Kọmanda ikọ RRS l’Ekoo, CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, ti taari awọn afurasi naa s’ẹka ọtẹlẹmuyẹ nileeṣẹ ọlọpaa fun iwadii to lọọrin, ki wọn le foju wọn bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply