Jimoh Aliu ti ku o

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ogbontagiri elere ori itage, Oloye Jimoh Aliu, ti jade laye.

 

Ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrun-un (86) ni gbajugbaja onitiata to jẹ ọmọ Okemẹsi Ekiti ọhun nigba tọlọjọ de lonii, Ọjọru.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ekiti to wa niluu Ado-Ekiti ni baba naa ku si, bẹẹ ni wọn n ṣeto lati gbe e lọ sile rẹ lagbegbe Adebayọ lọwọlọwọ, lati ibẹ ni wọn yoo si ti gbe e lọ si Okemẹsi, nibi ti yoo ti wọ kaa ilẹ lọla.

Leave a Reply