Jimoh fi ọgọrun-un naira tan ọmọ ọdun mejila wọ ṣọọbu rẹ, lo ba ba a lo pọ n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ileeṣẹ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, tipinlẹ Kwara, ti fi pampẹ ọba gbe baale ile ẹni ọdun marunlelaaadọta kan, Abdulraheem Jimoh, ti wọn fẹsun kan pe o ba ọmọ ọdun mejila lajọṣepọ lagbegbe Mayegun, laduugbo Alagbado, niluu Ilọrin.

Alukoro NSCDC, Babawale Zaid Afọlabi, ṣalaye ninu atẹjade kan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pe ọgọrun-un naira ni afurasi naa fi tan ọmọbinrin yii wọ ṣọọbu rẹ, biyẹn ṣe wọle lo ra a mu, to si run un wọ kọrọ kan, nibi to ti ba a sun.

ALAROYE gbọ pe lẹyin ti Jimoh ba ọmọ naa laṣepọ tan, o halẹ mọ ọn pe ko gbọdọ sọ fun ẹnikẹni, o ni to ba sọ ohun to ṣẹlẹ naa, oun maa pa a ni.

Afọlabi ni iru iṣẹlẹ bayii jẹ ohun to wọpọ lawujọ ti ko han si ọpọlọpọ eeyan. Laipẹ lo ni wọn yoo foju ọkunrin naa bale-ẹjọ.

Leave a Reply