Aderounmu Kazeem
Joe Biden, ọmọ ẹgbẹ oṣelu The Democratic Party, ti sọ pe ti wọn ba ti kede oun gẹgẹ bii aarẹ orilẹ-ede Amẹrika, niṣe ni ki gbogbo eeyan fọkan balẹ, nitori aarẹ daadaa loun yoo jẹ.
Lori ikanni abẹyẹfo ẹ, iyen Twitter, lo gbe e si, ohun to si sọ ni pe, “Ẹ jẹ ki n sọ ọ ko ye gbogbo yin daadaa o, loootọ ni mo polongo ibo gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu The Democratic Party, ṣugbọn mo fẹẹ fi da yin loju pe aarẹ orilẹ-ede awọn eeyan Amẹrika ni emi yoo jẹ, ki i ṣe aarẹ ẹgbẹ oṣelu ti mo dije loruko ẹ.”
Titi di asiko yii, ọkunrin naa lo ṣi n le waju, bẹẹ lo ti ni ibo to le ni ọtalelugba (264), latọwọ awọn aṣoju nipinlẹ kọọkan, nigba ti ibo gbogboo-gbo to ṣi ni bayii jẹ miliọnu mejilelaaadọrin-o-le (72,473,159).
Trump ni tiẹ ni ibo to fẹẹ to okoolelugba (214) latọwọ awọn aṣoju nipinlẹ kọọkan, nigba ti ibo gbogboo-gbo to ṣi ni bayii fẹẹ to miliọnu mọkandinlaaadọrin (68,908,642)
Olorun agbe debe