Jonathan n rin ni bebe ẹwọn o, ọmọ ọdun mẹẹẹdogun lo fipa ṣe ‘kinni’ fun ni Badagry

Jọkẹ Amọri

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn taari ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Jonathan Agbaje wa si kootu Majisreeti to wa niluu Badagry, nipinlẹ Eko. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹẹẹdogun kan lo pọ, o ṣi ṣe ọmọ naa baṣubaṣu.

Agbefọba Ikem Uko to wọn ọkunrin naa wa sile-ẹjọ ṣalaye peni nnkan bii aago mẹrin kọja ogun iṣẹju  ọjọ keji, oṣu kẹwaa, ọdun yii, lọkunrin naa huwa buruku ọhun ni Magbọn, niluu Badagry. Ẹsun meji to ni i ṣe pẹlu fifipa ba ọmọde lajọṣepọ ati ṣiṣe e baṣubaṣu.

Niṣe ni wọn ni o fọgbọn tan ọmọ naa wọnu yara rẹ lọ, to si n fika ro o ni oju ara titi to fi gba ibale rẹ lai jẹ pe ọmọ yii fara mọ ohun to ṣe.

Ẹṣẹ ti ọkunrin yii ṣẹ ni agbefọba ni o lodi sofin to de iwa ọdaran tipinlẹ Eko n lo.

Onidaajọ Patrick Adekomaiya to gbọ ẹjọ naa faaye beeli ẹgbẹrun lọna igba naira silẹ fun olujẹjọ pẹlu oniduuro meji ni iye kan naa

Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, ọdun yii.

 

Leave a Reply