Joshua fiya jẹ Pulev, ogbologboo abẹṣẹ-ku-bii-ojo

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Oriire nla mi-in ni Anthony Joshua, ọmọ Naijiria  to filẹ Britain ṣebugbe, ṣe loru ọjọ Aiku, Sannde, ni ibudo SSE to wa ni Wembley, niluu London, pẹlu bo ṣe gba bẹliiti IBF, WBA ati WBO pada lẹyin to koju Kubrat Pulev, to si fiya jẹ ọmọ Bulgaria naa.

Ija nla lo ṣẹlẹ lọjọ naa niwaju ẹgbẹrun kan oluworan to wa ninu gbọngan ọhun, eyi ti olokiki abẹṣẹ-ku-bii-ojo ọmọ Amẹrika nni, Floyd Mayweather, jẹ ọkan ninu wọn, ati ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan to wo ija naa kaakiri agbaye.

Bi ija naa ṣe bẹrẹ lo ti han pe Joshua, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, ati Pulev, ẹni ọdun mọkandinlogoji, ko ni i gba fun ara wọn. Ẹsẹ tawọn mejeeji n ju sira wọn ki i ṣe ṣereṣere rara, ṣugbọn Joshua lo rọwọ mu.

Ipele kẹta nija naa iba ti pari, nigba ti Joshua fi ẹṣẹ nla kan gbe Pulev ṣubu, ṣugbọn ọmọ Bulgaria naa sare dide, oun naa si da a pada, bo tilẹ jẹ pe ko lagbara bii ti Joshua.

Ipele kẹsan-an ni nnkan ti yiwọ fun Pulev patapata nitori o kọkọ ṣubu, o si sare dide, ṣugbọn nigba to ṣubu lẹẹkeji nipele naa, erin wo patapata ni, ko le dide mọ.

Pẹlu oriire tuntun yii, ija mẹẹẹdọgbọn ni Joshua ti ja, ninu eyi to ti yege ni mẹrinlelogun. Ninu ija wọnyi, igba mejilelogun lo gbe awọn alatako ẹ ṣubu ti wọn ko le dide.

Fun Pulev, igba keji ti yoo fidi-rẹmi ninu ija ọgbọn niyi. Ninu awọn ija naa, igba mẹrinla lo gbe awọn alatako ẹ ṣubu.

Ni bayii, ija Joshua ati Tyson Fury, ọmọ ilẹ Britain, to di ami-ẹyẹ WBC mu, lo ku, ireti si wa pe ọdun to n bọ ni yoo waye.

Leave a Reply