Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọmọ-ẹkọṣẹ kan, Josiah Godwin, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o ju oku ọga rẹ, Savior Joseph, sinu kanga lẹyin to pa a tan ti foju bale-ẹjọ Majisreeti to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ.
Ọmọkunrin ẹni ogun ọdun ọhun ni wọn fẹsun pe o mọ-ọn-mọ ṣeku pa ni ati ipaniyan kan lasiko to n fara han ni kootu laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ taa wa yii.
Iṣẹlẹ ọhun to waye lagbegbe Ìmàfọ̀n, niluu Akurẹ, ninu oṣu keji yii, ni wọn lo ta ko abala ọtalelugba-le-mẹsan-an ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Ọlọpaa agbefọba, Fọlaṣade Adeyẹmi, ni iwadii awọn ti fidi rẹ mulẹ pe ṣe ni olujẹjọ naa la nnkan mọ ọga rẹ titi to fi ku ko too ṣẹṣẹ lọọ ju oku rẹ sinu kanga.
Agbefọba ọhun ni oun dabaa ki wọn ṣi fi afurasi ọdaran naa pamọ sinu ọgba ẹwọn Olokuta, titi tile-ẹjọ yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Agbẹjọro fun olujẹjọ, Amofin Friday Adeoye, naa ni oun fara mọ aba yii.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Idowu Mayọwa gba ẹbẹ agbefọba wọle pẹlu bo ṣe ni ki wọn ṣi lọọ fi olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹtàdínlógún, oṣu Kẹta, ọdun 2023, nigba ti igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.