Joy ji ọmọọdun mẹta gbe l’Ekoo, o tun lọọ ji omi-in n’Ibadan

Faith Adebọla

Loootọ lawọn eeyan n daṣa pe ko sohun tọkunrin n ṣe tobinrin o le ṣe, ṣugbọn idi okoowo ibanujẹ lobinrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn yii, Joy Kọlapọ, tumọ ọrọ naa si ni tiẹ o, niṣe lo n ji awọn ọmọ ọlọmọ gbe kaakiri, to ba ti gbowo lọwọ awọn obi wọn, aa tu wọn silẹ, aa si tun lọ sagbegbe mi-in ti wọn o ti i fura si i, ni yoo ba tun j’ọmọ wọn gbe nibẹ lati gbowo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to fọrọ yii lede ninu atẹjade kan to fi sọwọ s’ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ogunjọ, oṣu Kọkanla yii, sọ pe ọjọ kejila, oṣu naa, lọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ tẹ afurasi ọdaran yii.

Wọn ni iṣẹlẹ ibanujẹ kan to waye niluu Ejigbo, ipinlẹ Eko, lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, to kọja yii, nibi tọmọ ọdun mẹta kan ti wọn porukọ ẹ ni Bright ti dawati lojiji, lo mu kawọn ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ si i fimu finlẹ, ti wọn n tọpinpin ibi teefin ajalu naa ti n ru wa. Iwadii ijinlẹ naa lo jẹ ki wọn roye pe Abilekọ Joy Kọlapọ ọhun lamookunṣika to ṣiṣẹ laabi ọhun, ati pe oṣika-tan-tẹsẹ-mọrin ẹda yii ti kuro l’Ekoo, eyi lo si gbe wọn deluu Ọmi-Adio, nijọba ibilẹ Ọmi-Adio, nipinlẹ Ọyọ, nibi tọwọ ti tẹ ẹ.

Nibi ti wọn ka afurasi naa mọ, wọn ba ọmọọdun meje kan, Moses, lakata ẹ, o ji ọmọ naa gbe ni, o si jẹwọ pe adugbo Olopo Mẹta, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, loun ti ji i gbe.

O tun jẹwọ pe ọdọ ẹnikan niluu Akute, nipinlẹ Ogun, loun tọju Bright ti wọn n wa l’Ekoo pamọ si.

Iwadii fihan pe alaamulegbe ni afurasi ọdaran yii jẹ sawọn obi Bright to sọnu, wọn jọ n gbe laduugbo kan naa l’Ejigbo ni, lẹyin to ji ọmọ naa gbe lo dibọn, o pe awọn obi ọmọ ọhun lori aago, o ni ki wọn waa fowo gba ọmọ wọn silẹ, o si gba ẹgbẹrun lọna marundinlọgọta Naira (N55,000) lọwọ wọn.

Ṣugbọn dipo ti iba fi fọmọ naa le awọn obi ẹ lọwọ, niṣe lo mu un lọ sọdọ ọrẹ ẹ kan to wa l’Akute, o ni kọrẹẹ oun yii jọọ, ba oun mojuto ọmọ naa tori oun fẹẹ yara ra awọn ọja pẹẹpẹẹpẹẹ kan lagbegbe ọhun, lo ba yọ ọmọ naa atọrẹ ẹ silẹ, o sa lọ rau.

Wọn ni nigba tọrẹẹ reti remu titi ti ko ri i niyẹn ba kọri si teṣan ọlọpaa lẹka ileeṣẹ wọn to wa l’Ojodu Abiọdun, lati lọọ fiṣẹlẹ naa to wọn leti, o si fa ọmọ ọhun le awọn ọlọpaa lọwọ.

Oun ko mọ pe ijẹ ana ti dun mọ ehoro Joy yii lẹnu, o ti tẹkọ leti lọ siluu Ibadan, nibi to ti tun lọọ ji Moses ti wọn ba lọdọ ẹ gbe.

Wọn lo ti gba ẹgbẹrun lọna ogun lọwọ awọn obi Moses ọhun, gẹgẹ bii owo itusilẹ ọmọ wọn, o ṣi n wa ibi to maa yọ ọmọde naa silẹ si, ko tun tẹsẹ mọrin, lawọn agbofinro ka a mọ.

Hundeyin ni yatọ si pe wọn toko iroko doko irokoto, o ni ko seyii to fara pa ninu awọn ọmọ mejeeji ọhun, awọn si ti fa wọn le awọn obi wọn lọwọ.

O lawọn ti pari iwadii lori iṣẹlẹ yii, awọn si ti fẹsẹ afurasi ọdaran naa le ọna ile-ẹjọ, o ti n kawọ pọnyin niwaju adajọ.

Leave a Reply