Jubril fẹṣẹ yọ eyin Mark l’Ọta, lo ba loun ko jẹbi

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọjọ Ẹti to kọja yii ni Abioye Jubril, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, foju ba kootu Majisireeti Ọta, nitori ọmọ Ibo kan, Mark Ugwuka, ti wọn jọ ja, to si fun un lẹṣẹẹ lẹnu debi ti eyin kan fi fo yọ lẹnu Mark, ṣugbọn Jubril loun ko jẹbi o.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2021, ni ija ṣẹlẹ laarin Jubril ati Mark, lopopona  kan ti wọn n pe ni Mẹsan, lagbegbe Iju-Ọta, nipinlẹ Ogun.

Agbefọba E.O Adaraloye ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ naa ni ija waye laarin olujẹjọ ati olupẹjọ, ti wọn lu ara wọn gidi. Nibi ti wọn ti n ja naa ni Jubril ti fun Mark lẹṣẹẹ lẹnu gẹgẹ bo ṣe wi, bi eyin kan ṣe fo yọ lẹnu Mark Ugwuka niyẹn.

Eyi ta ko awọn abala ofin kan ninu iwe ofin ipinlẹ Ogun ti wọn ṣe lọdun 2006, ijiya si wa fun un pẹlu. Ṣugbọn nigba ti Jubril ti wọn fẹsun kan loun ko jẹbi, Adajọ  A. O Adeyẹmi faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira (100,000) ati oniduuro kan niye kan naa.

Adajọ paṣẹ pe oniduuro naa gbọdọ niṣẹ lọwọ, o si gbọdọ le ṣafihan iwe owo-ori sisan rẹ fun ijọba ipinlẹ Ogun.

Igbẹjọ tun di ọjọ keje, oṣu keje, ọdun 2021.

Igbẹjọ mi-in ti yoo tun waye lọjọ keje naa ni ti  ọkunrin kan, Destiny Amadi, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ti kootu yii fẹsun kan pe o ji ọmọbinrin tọjọ ori ẹ ko ju mẹrindinlogun (16) gbe.

Awọn ọlọpaa lo mu Amadi, ẹni to n gbe lojule karun-un, Opopopona Iginla, Gas-Line, n’Ijoko Ọta, ipinlẹ Ogun. Ijinigbe ni wọn si tori ẹ mu un.

Inspẹkitọ E.O Adaraloye naa lo ṣoju ijọba lori ẹjọ yii, oun lo ṣalaye pe ọjọ kẹrin, oṣu kẹfa, ọdun 2021 yii, ni Amadi ji ọmọbinrin naa gbe.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ, Amadi loun ko ṣẹ ẹṣẹ tawọn ọlọpaa tori ẹ mu oun, nitori naa, oun ko jẹbi.

Majisireeti A.O Adeyẹmi naa lo gbọ ẹsun keji yii, o faaye beeli silẹ fun olujẹjọ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira ati oniduuro kan niye kan naa.

Oniduuro rẹ naa gbọdọ niṣẹ gidi lọwọ bi Adajọ ṣe wi, o si gbọdọ jẹ ẹni to n sanwo ori deede funjọba ipinlẹ Ogun.

Leave a Reply