Jumọkẹ binu para ẹ l’Ondo, nitori ti wọn fun un niwee gbele ẹ lẹnu iṣẹ

Jide Alabi

Titi di asiko yii ni iku oro ti ọmọbinrin kan, Jumọke Kẹhinde, ti ko ju ẹni ọdun mẹtalelogun lọ fi para ẹ ṣi n ya awọn eeyan lẹnu l’Ondo.

Ile itaja nla kan ni wọn sọ pe o ti n ba wọn taja niluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, ati pe l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, ni wọn fun un niwee gbele-ẹ nitori to pẹẹ de ibi iṣẹ. Ohun ti wọn lo fa a to fi gbe ogun jẹ niyẹn.

Ọkan lara awọn ọga ile itaja ọhun ṣalaye fawọn oniroyin pe loootọ lo pẹẹ de ibi iṣẹ lọjọ naa, ati pe bo ṣe de to n ṣiṣẹ ẹ lo n ṣọyaya pelu, ti ẹnikẹni ko mọ pe iku ti n kan ilẹkun lori ẹ.

O ni nigba to maa di bii aago mọkanla ni wọn fun un niwee gbele-ẹ, nitori to pẹẹ de, nigba to si maa di aago mẹrin irọlẹ, ipe pajawiri lawọn gbọ pe ara ọmọ naa ko ya gidigidi.

Ẹni to sọrọ yii sọ pe ki i ṣe Jumọkẹ nikan ni wọn fun niwee ọhun, gbogbo awọn ti wọn jọ pẹẹ de ni. O ni bi awọn ṣe gba ipe ̀̀ọhun lawọn ti sare ran ọkan ninu awọn ẹgbẹ rẹ lọọ wo o nile, tiyẹn si ba a nilẹẹlẹ nibi to ti n jẹ irora buruku.

O fi kun un pe bo tilẹ jẹ pe wọn ko ba agolo tabi ike majele to gbe jẹ nilẹ, sibẹ, niṣe ni ẹnu ẹ n run fun oogun apẹfọn to gbe mu.

ALAROYE gbọ pe ki Jumọkẹ too pa ara ẹ yii lo ti pe mama ẹ lori ẹrọ alagbeeka ẹ, to n sunkun yọbọ, nigba ti iya paapaa yoo si fi ran ni ki wọn lọọ wo o nile, Jumọkẹ ti gbe nnkan jẹ, nilẹẹlẹ lẹni ti wọn ran si i ti ba a ti wọn si sare gbe e lọ sileewosan. Nibẹ naa ni wọn ti sọ pe ọmọ naa ti ku.

Ọkan lara awọn akẹgbẹ ẹ sọ pe nile itaja ọhun, ti eeyan ba ti pẹẹ de, niṣe ni wọn maa ni ko lọọ sinmi diẹ nile, ti wọn yoo si yọ ninu owo-oṣu tọhun. O ni ko yẹ ki Jumọkẹ tori iyẹn para ẹ danu, nitori ohun ti gbogbo awọn mọ ni.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ̀ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ti sọ pe awọn ko ti i gbọ si iṣẹlẹ ọhun, ati pe ni kete ti wọn ba ti fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti ni igbesẹ to yẹ yoo waye.

Ni bayii, wọn ni wọn ti gbe oku Jumọkẹ, pamọ sile igbokuu-si ni ileewosan yunifaisti niluu Akurẹ.

Leave a Reply