Faith Adebọla, Eko
Abilekọ ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Justin Eje, ti n ṣalaye bọrọ ṣe jẹ fawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn mu un lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, latari bi wọn ṣe lobinrin naa jẹwọ pe loootọ loun gun ọkọ oun, Edwin Anduaka, lọbẹ nigba tawọn n fa ọrọ kan, ṣugbọn oun o mọ pe iṣẹlẹ naa le la iku lọ.
Tọkọ-taya ni Justin ati Edwin, gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọmọ mẹta lo ti wa ninu igbeyawo wọn, agbegbe Ikorodu, nipinlẹ Eko, si lawọn mejeeji n gbe.
Ninu alaye ti obinrin naa ṣe fawọn ọlọpaa to n ṣewadii, o ni oun ati oloogbe naa ti ja lati ọdun to kọja, oun si ti lọ n gbe pẹlu awọn ọmọ oun ni ile kan toun rẹnti, o ni ile naa ko fi bẹẹ jinna si adugbo tawọn n gbe tẹlẹ, oun si maa n se indomie ati ẹyin ta labẹ buka kan toun kọ si adugbo naa.
Justin ni lọjọ buruku ọhun, niṣe loun ri ọkọ oun laaarọ, o waa ba oun, o loun fẹẹ gba awọn ṣeeni (ẹgba ọrun ati tọwọ) kan to fẹsun kan oun pe o wa lara ẹru toun ko jade ninu ile rẹ, o tun loun ko awọn aṣọ oun kan.
Afurasi ọdaran naa ṣalaye pe “Oju ẹsẹ ni mo tu apoti aṣọ mi, mo si fun un lawọn nnkan to loun fẹẹ gba. Bo ṣe gba awọn nnkan naa tan lo n leri si mi pe oun ṣi maa ba mi fa wahala o, oun maa ba mi fa ijangbọn gidi, ki n yaa lọọ mura silẹ. Emi si da a lohun pe emi o raaye wahala ni temi, oun ni ko maa ba ara ẹ fa nnkan to ba fẹẹ fa, bẹẹ lo ṣe lọ laaarọ yẹn.
“Igba to di irọlẹ, ni nnkan bii aago mẹta, lo tun de, abẹ buka ti mo ti n taja lo ti waa ba mi, mo n din ẹyin fun kọsitọma mi kan lọwọ nigba yẹn, o ni aṣọ toun fowo oun ra fawọn ọmọ nkọ, pe ki n ko o foun, mo si fesi pe ko ni suuru kawọn ọmọ de, o ṣaa ri i pe wọn o ti i ti ileewe de, ati pe mo n taja lọwọ bayii, ko jẹ kawọn ọmọ naa de ki wọn ko aṣọ to n sọrọ ẹ fun un funra wọn.
“O fariga pe oun o le duro de awọn ọmọ, ki emi fi nnkan ti mo n ṣe silẹ, mo si ni iyẹn o le ṣee ṣe. Ọrọ yii lo dija laarin wa, bo ṣe bẹrẹ si i lu mi niyẹn, o gba mi leti, o tun fibinu da ọja mi nu. Ọbẹ ti mo fi fọ ẹyin ṣi wa lọwọ mi nigba yẹn, bemi naa ṣe ki ọbẹ si i nikun niyẹn, lo ba fidi janlẹ.
“Awọn aladuugbo sare sun mọ wa, a si jọ gbe e lọ sọsibitu aladaani to wa nitosi, ṣugbọn o ti dakẹ ka too de ọsibitu naa.”
Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, ni iwadii ṣi n lọ lori iṣẹlẹ yii, awọn agbofinro si ti gbe oku baale naa lọọ fun ayẹwo lọsibitu ijọba.