Ka too dibo la ti mọ pe ‘one chance’ ni Gomina Abdulrazak ta a yan -Lai Muhammed

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gbogbo awọn to gbọ ọrọ to n ti ẹnu Minisita feto iroyin nilẹ wa, Alaaji Lai Muhammed, jade nibi ipade ita gbangba kan to ṣe pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara, lo ti mọ pe tirela ti gba aarin oun ati Gomina ipinlẹ naa bayii, AbdulRahaman AbdulRazaq, kọja.

Eyi ko sẹyin fidio kan to n ja rain-in kaakiri ori ẹrọ ayelujara, nibi ti minisita naa ti n sọrọ buruku si gomina yii atawọn ohun to ṣe ti ko dun mọ ọn ninu.

Lai Muhammed ni, ‘‘Owo gbogbo awọn aṣaaju wa la ni ki wọn fi ṣe kokaari eto idibo naa, mo ṣi ni ẹlẹrii. A pin owo, a pin ọkada, a si pin mọto, ṣe oun fi kọbọ silẹ nibẹ ni. Bawo lo ṣe ro pe awa ṣe maa wọle, ta a ba dibo.

‘‘Ka tiẹ too yan an ni gomina la ti mọ pe a ti wọ ‘one chance’. Amọ Ọlọrun Ọba mi, Ọba eleto ni, o ti mọ pe bi yoo ṣe ri niyẹn. Ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ohun ti wọn ro pe a ko le ṣe, a ṣe e.

‘‘Amunibuni ni, o waa jẹ ọmọ ẹgbẹ wa tẹlẹ, a ko mọ ọn ri, ojo lo ko ẹyẹle pọ mọ adiẹ, a ro pe eeyan ni wọn ni. Ohun to wa lọkan wa ni pe ka le ẹlẹyọrọ lọ, ka too fabọ fun adiẹ.’’

Bi fidio naa ṣe lọ niyẹn. Ṣe ki i ṣe tuntun mọ pe ẹgbẹ oṣelu APC ti pin yẹlẹyẹlẹ ni Kwara, ija ojoojumọ ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa si n ba ara wọn ja.

Leave a Reply