Kaadi idibo: Ijọba kede ọjọ Ẹti gẹgẹ bii isinmi fawọn oṣiṣẹ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ fawọn oṣiṣẹ, ki wọn le lanfaani lati lọọ gba kaadi idibo wọn.
Gẹgẹ bii atẹjade kan ti akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Wọle Oyebamiji, fi sita lọsan-an Tọsidee, o ṣalaye pe ijọba fi anfaani yii silẹ fawọn ti wọn ko ti i gba kaadi idibo wọn lati ṣe bẹẹ.
Oyebamiji ṣalaye pe lara ẹtọ gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ni lati gba kaadi idibo wọn, ki wọn le lanfaani lati dibo fun aṣaaju ti wọn ba fẹ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.

O ṣalaye siwaju pe lai si kaadi idibo, ko le ṣee ṣe fun awọn oṣiṣẹ ijọba lati yan ijọba ti yoo mu ọrọ igbaye-gbadun wọn lọkun-un-kundun.
O ni idi niyi ti ijọba ko ṣe fẹ ki anfaani gbigba kaadi idibo yii fo ẹnikẹni da, ti ijọba si ṣe fi anfaani silẹ fun wọn lati lọ gba kaadi naa.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: