Kalu to yinbọn lu Adija nitori ounjẹ l’Abẹokuta ti wa lẹwọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Kootu Majisireeti to n jokoo l’Abẹokuta ti paṣẹ pe ki wọn ju ọkunrin kan, Obinna Kalu, sọgba ẹwọn Ibara, l’Abẹokuta, titi di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii, nitori ayalegbe bii tiẹ, Adija, to yinbọn lu nigba tiyẹn fẹsun kan an pe o bu ninu ounjẹ toun n ta lai sọ foun.

ASP Ọlakunle Ṣọnibarẹ, agbefọba to ka ẹsun si kootu leti lọjọ Ẹti to kọja yii, ṣalaye pe ọjọ kẹrinla, oṣu kẹta, ọdun 2012, niṣẹlẹ naa waye laduugbo Igaa Sabo, l’Abẹokuta.

Ṣọnibarẹ ṣalaye pe ounjẹ ni Adija n ta, bo ti dana tan lọjọ naa lo wọle lọ. Nigba ti yoo fi jade pada lo ri i pe ẹnikan ti bu ninu ounjẹ naa lai sọ foun.

A gbọ pe ija ti wa nilẹ tẹlẹ laarin Kalu ati Adija, Kalu ọhun naa ni Adija tun waa fẹsun kan pe o ji ounjẹ oun bu lai sọ foun. Nigba ti obinrin naa tun waa fẹsun ole kan an yii, o dun ọkunrin Ibo naa pupọ, ọrọ naa si di ariwo ninu ile wọn.

Awọn araale ba wọn yanju ẹ, wọn si ni ki kaluku wọn ma binu, ki wọn jẹ ko tan sibẹ. Awọn eeyan ṣebi o ti tan lọkan Kalu naa ni, aṣe ọrọ naa ṣi ku nibẹ.

Nigba ti ile ti da, ti Adija ti wọ yara ẹ lati rẹju ni Kalu yọ wọ yara obinrin naa, o si yinbọn fun un lẹgbẹẹ, lo ba sa jade.

Fun ọjọ bii meloo kan, Kalu ko wale, niṣe lo sa lọ lẹyin to ṣiṣẹ ibi naa. Adija to yinbọn lu ri i pe oun lo yinbọn naa, ariwo rẹ naa lo si fi bọnu. Nigba tawọn eeyan tun waa ṣakiyesi pe Kalu ti sa lọ nile, kaluku gba pe oun lo ṣiṣẹ naa loootọ.

Nnkan bii ọjọ kẹta lẹyin to sa kuro nile lọwọ ọlọpaa tẹ ẹ, wọn si mu un ṣinkun gẹgẹ bii ọdaran ti wọn ti n wa tẹlẹ.

Ọrọ naa ti figba kan wa ni kootu, ko too di pe awọn ile-ẹjọ daṣẹ silẹ. Nigba ti wọn si tun jokoo nipa ẹ lọsẹ to kọja yii, Adajọ Abilekọ O.M Ṣomẹfun, paṣẹ pe ki wọn gbe Kalu lọ sẹwọn Ibara, ko wa nibẹ titi di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, nigba ti ẹka DPP to n da si ọrọ bii eyi yoo ti mu amọran wọn wa.

Leave a Reply