Kansilọ atawọn alaga kansu tuntun ipinlẹ Ọyọ bẹrẹ iṣẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn kansilọ atawọn alaga kansu tawọn araalu ṣẹṣẹ dibo yan ninu idibo ijọba ibilẹ to waye jake-jado ipinlẹ naa lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, ti bẹrẹ iṣẹ lọfiisi kaluku wọn bayii.

Eyi waye lẹyin ti Onidaajọ Munta Abimbọla ti i ṣe adajọ agba ipinlẹ Ọyọ bura fun wọn nileegbimọ awọn lọbalọba ipinlẹ naa to wa l’Agodi, n’Ibadan, nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ṣaaju, iyẹn laaarọ ọjọ Aje naa lalaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, OYSIEC, Amofin-Agba Aarẹ Isiaka Abiọla Ọlagunju, ti fun awọn alaga ati kansilọ to jawe olubori ninu idibo naa niwee ẹri gẹgẹ bii ẹni ti awọn araalu dibo yan sipo ti kaluku wọn wa lasiko idibo to kọja.

Lẹyin ti adajọ agba bura fun wọn tan ni Makinde gba awọn alaga ati kansilọ yii niyanju lati ṣamulo ilana iṣejọba oun lati le mu idagbasoke ba agbegbe kaluku wọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ,”Ko si nnkan ta a le fi we idagbasoke ati iṣejọba rere. Ni bayii, anfaani ti wa fun yin lati mu iṣejọba rere wọ ijọba ibilẹ tabi agbegbe yin. Nnkan ti awọn araalu si n reti lọdọ yín naa niyẹn.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejilelogun, oṣu karun-un, ọdun 2021, ta a wa yii nidibo ijọba ibilẹ waye kaakiri ijọba ibilẹ mejilelọgbọn, ninu ijọba mẹtalelọgbọn to wa ni ipinlẹ Ọyọ.

Ibo ijọba ibilẹ Ido nikan ni wọn ko ti i di nitori ti ajọ eleto idibo ko ranti fi ami ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party (ZLP) sinu iwe idibo.

Awọn oludije lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP lo jawe olubori kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ mejeejilelọgbọn (32) ti wọn ti dibo wọn nigba ti idibo ijọba ibilẹ Ido to ṣẹku yóò waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Ba a ṣe n wi yii, awọn kansilọ atawọn alaga kansu tuntun naa ti bẹrẹ iṣẹ lọfiisi kaluku wọn latọjọ Iṣẹgun, Tusidee.

Leave a Reply