Kaosarah, ẹni ọdun mẹrinlelogun, di kọmiṣanna ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Akẹkọọ-jade ẹni ọdun mẹrinlelogun kan to pari ẹkọ rẹ ni Fasiti Ilọrin, Adeyi Kaosarah, wa lara awọn orukọ mẹjọ ti Gomina Abdulrahman Abdulrazaq fi ranṣẹ sile aṣofin lati buwọ lu sipo kọmiṣanna.

Ninu awọn mẹjọ naa, obinrin mẹrin wa lara wọn.

Ọdun 2019 ni Kaosarah pari ẹkọ rẹ ko too lọọ ṣeto agunbanirọ lati sin ijọba nipinlẹ Ọyọ.

Ọmọ bibi ilu Ilọrin, lati Wọọdu Ojuẹkun-Sarumi, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin (Ilọrin West), ni ọmọbinrin naa.

Lara ipo to ti dimu ri ni igbakeji aarẹ fun ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni Fasiti Ilọrin, o tun jẹ ọkan lara awọn ọmọ igbimọ to n ṣewadii ifiya jẹ araalu latọwọ awọn ọlọpaa SARS.

Aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni ile aṣofin naa kede rẹ nibi ijokoo wọn.

Orukọ awọn kọmiṣanna yooku tile naa kede ni; Rotimi Suleiman Iliasu, Lafia Aliyu Kora Sabi, Hajia Saadat Modibbo Kawu, Hajia Arinola Lawal, Kaosarah Adeyi, Dokita Raji Razaq, Aliyu M. Saifuddeen ati Fẹmi White.

Mẹrin lara awọn kọmiṣanna tẹlẹ; Rotimi Suleiman Iliasu, Hajia Saadat Modibbo Kawu, Hajia Arinola Lawal, Dokita Raji Razaq, lo tun maa pada.

Leave a Reply