Kayeefi! Iyaale ile yii ji ara rẹ gbe, lo ba ni kileeṣẹ oun waa sanwo itusilẹ

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Edo, nipinlẹ Edo, ni iyaale ile kan, Abilekọ Blessing Ogunu, atawọn ọrẹ rẹ meji kan, Abilekọ Esther Anthony ati Ogbẹni Ukpebor Joel wa, wọn n ran awọn ọlọpaa naa lọwọ ninu iwadii wọn lori ẹsun tawọn agbofinro fi kan wọn pe Blessing ji ara rẹ gbe pamọ, o si n beere fun owo itusilẹ lọwọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ aladaani kan to n ba ṣiṣẹ.

ALAROYE gbọ pe miliọnu marun-un din diẹ Naira (N4.8M) lowo ti Blessing n beere lọwọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ‘Bliss Legacy Limited’, to wa niluu Benin-City ko too di pe wọn gba a mu nibi to sapamọ si.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Chidi Nwabuzor, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, sọ pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ adani kan ti wọn n ba ṣiṣẹ ni wọn waa fọrọ ijinigbe ọhun to awọn ọlọpaa leti, tawọn yẹn fi bẹrẹ iwadii nipa iṣẹlẹ ọhun.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘‘Laipẹ yii lawọn alaṣẹ ileeṣẹ aladaani kan ti Blessing n ba ṣiṣẹ waa fọrọ ijinigbe kan to wa leti, wọn sọ pe awọn ajinigbe ji ọkan lara awọn oṣiṣẹ awọn gbe lọ, wọn si n beere fun owo itusilẹ. A bẹrẹ si i ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun, a fọwọ ofin mu Blessing atawọn isọngbe rẹ meji kan nibi ti wọn sapamọ si, Blessing paapaa jẹwọ pe oun gan-an loun mu aba buruku ọhun wa lati gbẹsan lara awọn ọga oun nibi iṣẹ, nitori pe wọn gbowo nla kan lọwọ onibaara toun mu wa fun wọn, ti wọn ko si fun onitọhun nilẹ to fẹẹ ra lọwọ wọn.

Alukoro ni awọn maa too foju gbogbo wọn bale-ẹjọ.

 

Leave a Reply