Kayeefi nla leleyii o! Baba fun ọmọ bibi inu ẹ ẹ loyun n’Ikorodu

  • Chibuike naa tun fipa bọmọ ọdun mẹrinla lo pọ ni Bariga
  • Bẹẹ ni Chinedu ṣe kinni fawọn ọmọ ọga ẹ l’Aguda

Faith Adebọla, Eko

Chinedu to fipa bawọn ibeji ọga ẹ lo pọ

Baba ẹni ọdun mọkanlelọgọta kan, Eke Kanu ko ribi to maa ti ‘kinni’ ẹ bọ mọ, ọmọ bibi inu ẹ lo ba lo pọ titi tọmọ ọhun fi loyun mọ ọn lọwọ.

Awọn ọlọpaa teṣan ilu Ikorodu ni wọn sọ pe ọkan lara awọn lanlọọdu agbegbe naa mu ẹsun Eke wa sọdọ awọn nirọlẹ ọjọ kejila, oṣu yii, pe ọkunrin naa n ba ọmọ to bi ninu ẹ to jẹ ẹ ẹni ọdun mọkandinlogun laṣepọ.

Eyi lo mu kawọn ọlọpaa ṣaa gbera lọ sile afurasi naa to wa lọna Ebute, laduugbo Igbogbo, n’Ikorodu, ṣugbọn wọn ko ba baba naa. Wọn ba ọmọ ẹ ta a forukọ bo laṣiiri naa, wọn si beere ọrọ lọwọ rẹ.

Ọmọ ọhun jẹwọ fun wọn pe loootọ ni baba n ba oun lo pọ, ko si ṣẹṣẹ maa ṣe bẹẹ paapaa. O ni kekere loun wa to ti n ṣe ‘kinni’ foun, oun lo si gba ibale oun.

Ọmọbinrin yii fi kun un pe baba oun ni ti awo ọrọ naa ba fi lu latọdọ oun, oun aa foju oun ri mabo. Eyi lo ni ko jẹ koun sọrọ naa fẹnikẹni, afigba ti aṣiri ọrọ naa tu pẹlu bi oyun ṣe wọ ọ. Gbogbo ọna lo ni baba naa ti wa lati ṣẹyun naa pẹlu bo ṣe gbe oun lọ sọdọ kẹmiisi (chemist) pe ko ba oun yọ ọ sọnu, wọn si loogun foun,  l’Ọlọrun lo yọ ẹmi oun.

Awọn ọlọpaa ti mu ọmọbinrin naa lọ sileewosan Mirabel Center, fun ayẹwo, wọn si dọdẹ Kanu titi tọwọ fi to o, igba ti wọn si bi i leere ọrọ, o ni ko sirọ nibẹ, bọrọ ṣe ri lọmọ oun sọ yẹn.

Wọn ti fi baba naa ṣọwọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ (CID) ni Panti, Yaba, fun iwadii, ki wọn too taari ẹ sile-ẹjọ gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana, ṣe wi.

Bakan naa lọwọ ọlọpaa teṣan Bariga tun tẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Chibuike Kalu, ti wọn fẹsun kan pe o fipa laṣepọ pẹlu ọmọ ọdun mẹrinla kan ni Bariga.

Awọn obi ọmọbinrin ọhun lo mu ẹjọ Chibuike wa si tẹṣan, lawọn ọlọpaa ba lọọ fi pampẹ ofin gbe e l’Opopona Amodu, to n gbe.

Wọn ni Chibuike ti jẹwọ pe loootọ loun huwa ọdarun ọhun, ṣugbọn o bẹbẹ pe ki wọn ṣaanu oun.

ALAROYE gbọ pe wọn ti gbe ọmọbinrin naa lọ fun ayẹwo ati itọju lọsibitu kan n’Ikẹja, wọn si ti n to iwe ẹsun afurasi yii papọ lati taari ẹ siwaju adajọ lọsẹ yii.

Bẹẹ lobinrin kan tọjọ ori ẹ ko le ju ọdun marundinlogoji lọ kegbajare lọ si teṣan ọlọpaa Aguda pe ọmọọṣẹ oun, to n ba oun taja ni ṣọọbu, Chinedu Obi, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ti fipa ba ọkan ninu awọn ibeji oun ti ko ju ọdun mejila lọ laṣepọ.

Mama ibeji ọhun sọ pe niṣe loun fi awọn ibeji ọhun sọ ọmọkunrin naa nigba toun fẹẹ lọọ ra ọja lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣe to kọja lọhun-un. Lo ba fọgbọn tan ọkan ninu wọn si kọrọ yara kan ninu ile ti wọn n gbe, o si fipa ba a lo pọ. Obinrin yii ni iwadii oun fi han pe lati ọdun to kọja lo ti n fipa ba ọkan lara awọn ẹjirẹ naa sun.

Bala Elkana ti ṣe alukoro ọlọpaa sọ f’ALAROYE ninu atẹjade kan pe wọn ti mu Chinedu, oun naa jẹwọ pe loootọ loun ṣe ọmọ ọga oun baṣubaṣu. O ni latọdun 2019 loun ti n ṣe e, niṣe loun si halẹ mọ ọn pe ko gbọdọ tu aṣiri ọrọ naa sita, ati pe oun fẹẹ fẹ ẹ niyawo to ba ya ni.

O ti wa lakata awọn ọlọpaa to n wadii ọrọ to ba jẹ mọ biba ọmọde ṣeṣekuṣe, o si ṣee ṣe ko balẹ sile-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply